Faith Adebọla, Eko
B’ina o ba tan laṣọ, ẹjẹ o ni i tan leeekanna nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fọrọ awọn afurasi ọdaran, awọn janduku, awọn ẹlẹgbẹ okunkun atawọn to n da ilu ru, ṣe lopin ọsẹ ta a wa yii, wọn ni mẹtadinlọgbọn lara wọn lawọn mu lawọn ibuba wọn to wa kaakiri ipinlẹ Eko.
Alukoro awọn ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, lo fọrọ ọhun to ALAROYE leti lori ikanni agborokaye, Wasaapu rẹ, o ni latọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn ti ko si ọrọ wiwa awọn ọmọ adaluru ọhun, titi fi di afẹmọjumọ ọjọ Aiku, Sannde yii, si lawọn n ṣa wọn nikọọkan ejeeji kaakiri awọn ibi ti wọn mori mu si nipinlẹ Eko.
Lara awọn mẹtadinlọgbọn tọwọ ba naa ni: Kọlawọle Ọlajide, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Kẹhinde Ayọọla, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Dọla Abdullahi, ẹni ogun ọdun ati Micheal Ogungbade, ẹni ọdun mọkandinlogun, atawọn mẹtalelogun mi-in.
Adejọbi ni lati adugbo kan ti wọn n pe ni Ile-Zik, lọọ de abẹ biriiji Dọpẹmu, titi de Shasha, Orisunmbare lawọn ti fi pampẹ ofin gbe awọn ọmọ ganfe ọhun. O lawọn tun de Iyana-Ipaja, Ile-Epo, Abule Ẹgba, Isọkoko, Alfa Nla, Ọna Capitol l’Agege, Akilo, Marketing, Alausa CBD, n’Ikẹja.
Wọn ni ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa Rapid Respond Squard, RRS, ni wọn dojukọ iṣẹ ọhun, wọn si ṣe e bii iṣẹ gidi ni. Ọpọ awọn nnkan ija oloro lo lawọn ọlọpaa ba lọwọ awọn afurasi naa, bẹẹ ni wọn tun ka awọn egboogi oloro rẹpẹtẹ bii igbo, kokeeni atawọn mi-in mọ wọn lọwọ.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Hakeem Odumosu, ṣe paṣẹ, Adejọbi lawọn ti taari awọn afurasi wọnyi si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ni Yaba, fun iṣẹ iwadii. O ni ibẹ ni wọn maa wa titi ti wọn fi maa dero kootu laipẹ.
Adejọbi ni kawọn janduku tọwọ o ti i ba maa reti awọn laipẹ, tori ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i sinmi lori ọrọ wọn, afi ti wọn ba jawọ lo ku.