Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ọgba ẹwọn to wa niluu Ado-Ekiti, lawọn afurasi marun-un tẹ ẹ n wo yii wa lọwọlọwọ lẹyin ti wọn foju bale-ẹjọ lori ẹsun ṣiṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun, oṣu yii si ni igbẹjọ wọn yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Irin-ajo Sanni Mohammed (ẹni ọdun mọkandinlogun), Fagbẹhingbe Ayọdeji (ẹni ogun ọdun) Ojo Ademọla (ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn), Fatuki Tosin (ẹni ọdun mejidinlọgbọn) ati Arowoṣẹgbẹ Okiki (ẹni ogun ọdun) sọgba ẹwọn bẹrẹ lọjọ kẹsan-an, oṣu to kọja, nigba tọwọ ọlọpaa tẹ wọn niluu Ikẹrẹ-Ekiti.
Gẹgẹ bi alaye tawọn ọlọpaa ṣe fun akọroyin wa, awọn araalu lo sọ nipa awọn eeyan ọhun ti ikọ agbofinro kan fi lọọ ka wọn mọ ibi ti wọn ti n ṣeto igbaniwọle lọwọ. Lasiko ti wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo ni wọn jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun AIYE lawọn.
Awọn ọlọpaa ni ọkan ninu wọn, Sanni ti inagijẹ rẹ n jẹ Tom-Tom, tilẹ ti ṣẹwọn ri fun ẹsun kan naa, iyẹn ni bii ọdun kan sẹyin.
Nigba ti akọroyin wa lanfaani lati ba Sanni sọrọ, ọmọkunrin naa ni loootọ loun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn oun ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn ni, iyẹn lọdun to kọja, bẹẹ loun ko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ mi-in ju awọn ti wọn mu pẹlu oun yii.
O ni ile ọti kan niluu Ikẹrẹ-Ekiti ni wọn ti waa ko awọn, ki i ṣe ibi tawọn ti n ṣe igbaniwọle, ati pe aṣọ alawọ yẹlo to wa lọrun awọn yii ni ẹnikan to n ṣe ọjọọbi ni kawọn wọ waa ṣe faaji nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe oun lawọn ọlọpaa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ọga awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa, Sanni ni awọn ni ọga kan tawọn n pe ni Fẹla, ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, lo si n gbe.
Bakan naa ni ko jiyan nipa ẹwọn ti wọn lo ṣe ri, o ni ko si irọ ninu iyẹn, ṣugbọn oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun to n paayan tabi da wahala silẹ.
Nigba tawọn afurasi naa foju bale-ẹjọ Majisreeti-agba to wa niluu Ado-Ekiti, Inspẹkitọ Bankọle Ọlasunkanmi fidi ẹ mulẹ pe lẹyin tawọn ọlọpaa mu wọn ni wọn ba aake nile ọkan ninu wọn, eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi, ati pe awọn eeyan naa ti jẹwọ pe loootọ lawọn n ṣe ẹgbẹ okunkun.
O waa ni ki kootu naa fi wọn pamọ sọgba ẹwọn, ki ẹka to n ṣegbẹjọ araalu (DPP) le tan imọlẹ sọrọ wọn pẹlu bi wọn ṣe jẹbi abala kẹrin ofin to ta ko ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, eyi tijọba ṣagbekalẹ lọdun 2017.
Nitori bi ẹjọ wọn ṣe ri, akọwe kootu ko beere lọwọ wọn boya wọn jare tabi jẹbi, Majisreeti-agba Adedayọ Oyebanji si paṣẹ pe ki wọn maa lọ sọgba ẹwọn na.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, nigbẹjọ wọn yoo bẹrẹ.