Faith Adebọla
Awọn agbaagba iha Ariwa ilẹ wa ti rọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati tete kọwe fipo silẹ nipo aarẹ to wa, latari bi ipakupa, ifẹmiṣofo ati akọlu awọn agbebọn ṣe n tubọ n gogo si i lai dawọ duro kaakiri orileede yii.
Atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ wọn, Northern Elders Forum, Ọmọwe Hakeem Baba-Ahmed, fi lede lọjọ Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin yii, sọ pe ohun to foju han kedere ni pe ijọba Buhari ko ni ojuutu si ipenija eto aabo to dẹnu kọlẹ lasiko yii, wọn lọrọ naa ti kọja agbara ijọba rẹ.
Atẹjade ọhun ka lapa kan pe:
“Ko jọ pe ọgbọn kan tun wa ti iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari tun le ta si iṣoro aabo to mẹhẹ, eyi to n ba wa finra gidigidi lasiko yii. A o le maa gbe labẹ ihalẹ ati akọlu awọn apaayan, awọn ajinigbe, afipabanilopọ, atawọn ọdaran loriṣiiriṣii ti wọn o jẹ ka fẹdọ lori oronro mọ lorileede yii, ti wọn sọ alaafia wa di fia fia, ti eto aabo si ti dẹnu kọlẹ.
“Ofin orileede wa sọ pe ki olori kuro lori aleefa to ba ri i pe agbara oun ko gbe e mọ, tabi to ba foju han pe ṣiṣe olori ti fẹẹ pin in lẹmi, ti ko si sojuutu si ipenija to n koju.
“O ti tasiko wayi fun Aarẹ Buhari lati ṣepinnu kikọwe fipo silẹ, niwọn igba ti iṣejọba rẹ ti kuna, ikuna ti ki i ṣe kekere, lati pese aabo to peye fawọn ọmọ Naijiria.
“Awa agbaagba ilẹ Hausa mọ pe ọrọ ki aarẹ kọwe fipo silẹ ki i ṣe ọrọ ṣereṣere, awa naa o si fi i ṣe ọrọ apara rara, tori a o le maa gbe labẹ inu foo, aya foo, lai si ifọkanbalẹ rara, titi di ọdun 2023 ti saa iṣakoso Aarẹ Buhari maa kogba sile.”
Awọn agbaagba naa tun fi aidunnu wọn han si ijakulẹ ijọba to wa lode yii, lori ọrọ aabo, wọn ni niṣe ni ẹjẹ n fojoojumọ ṣan, paapaa lapa Oke-Ọya, o si ya awọn lẹnu pe ara Oke-Ọya naa lo wa lori aleefa ti iwọnyi fi n ṣẹlẹ.
Wọn ke si awọn eeyan to le ba Buhari sọrọ nibi ti yoo ti gbọ, pe ki wọn ma ṣe jafara lati gba ọkunrin naa lamọran pe ko kọwe fipo silẹ.
Wọn ni ipakupa ati ifẹmiṣofo ti waa di ọrọ ojumọ kan iṣẹlẹ kan, ti ko sẹni tọkan ẹ tun balẹ lati rinrin-ajo lọ sibikibi mọ, bẹẹ lawọn to wa labẹ orule wọn paapaa ko le sun oorun asunwọra rara.
“O daju pe awọn apaayan atawọn ọdaran wọnyi ti ri i pe ọrọ naa ko ye ijọba mọ, idi ree ti wọn fi n gbojugboya si i lojoojumọ, ti wọn si n lọ latori buburu si buburu ju, wọn fẹẹ doju ijọba ati eto aabo de raurau.
“Ẹmi awọn ọmọ Naijiria to ṣofo yii to gẹẹ. Awọn ti wọn ni ojuṣe lati daabo bo wa ko ri ọgbọn ta si i mọ, ẹ jẹ kẹlomi-in tun gbiyanju ẹ wo na.”
Bẹẹ lawọn agbagba naa kegbajare ninu atẹjade wọn.