Awọn agbanipa yinbọn pa Abdulfatai to n dupo Magaji niluu Ballah, ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni awọn kan ti wọn ko ti i mọ pa Abdulfatai Mọgaji, ẹni to n dupo Magaji Zeni. O ni Ọga ọlọpaa, Muhammed Bagega, ti paṣẹ pe ki iwadii to peye lori iku ọkunrin naa waye, ati pe ọwọ gbọdọ tẹ awọn to ṣeku pa a.

Awọn agbebọn kan ti wọn fura si pe wọn jẹ agbanipa ni wọn yinbọn pa ọkunrin yii lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niwaju ṣọọbu rẹ ni Ballah, lagbegbe Ẹyẹnkọrin, nipinlẹ Kwara.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe iwaju ṣọọbu rẹ ni Abdulfatai jokoo si lọjọ iṣẹlẹ naa, nibi tawọn gende mẹrin kan ti de lori ọkada, bi wọn si ṣe bọ silẹ, ọdọ rẹ ni wọn lọ taara, ti wọn si gbebọn fun un.

Ọkunrin ọhun lawọn eeyan mọ daadaa gẹgẹ bii ẹni to n ta ilẹ lagbegbe naa.

Wọn ni nigba tawọn yẹn de ibi toun pẹlu ẹnikan jokoo si, wọn ko tiẹ beere ọrọ kankan lọwọ rẹ, oju ẹsẹ ni wọn yinbọn fun un, ti wọn si poora kiakia. Ọkunrin naa ko lo iṣẹju kan to fi dagbere faye.

ALAROYE gbọ pe wọn ti sinku oloogbe naa nilana Musulumi nile mọlẹbi rẹ to wa lagbegbe Alanamu.

Ṣaaju asiko ti wọn pa a, Abdulfatai ti gba kootu lọ lati pẹjọ ta ko ẹni to wa nipo Magaji Zeni, Alhaji Sulaiman, ẹni toun pẹlu ẹ jọ dupo naa bii ọdun diẹ sẹyin.

Ile-ẹjọ giga tilu Ilọrin to gbọ ẹjọ naa ti da a lare ninu idajọ rẹ, ṣugbọn eyi ko dun mọ Alhaji Sulaiman ninu, idi toun naa fi gba ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun lọ niyẹn, ibi ni ile-ẹjọ ti kede pe oun ni ipo naa tọ si.

Abdulfatai ko waa duro sibẹ, oun naa gbe ẹjọ lọ si ile-ẹjọ to ga ju lọ, ibẹ lẹjọ ọhun ṣi wa titi digba ti wọn fi gbẹmi rẹ.

Ko sẹni to le sọ ibi ti iku ọkunrin naa ti wa, ṣugbọn iwadii awọn ọlọpaa ti n lọ lọwọ lori iku to pa a ati awọn to wa nidii rẹ.

Leave a Reply