Jọkẹ Amọri
Ko din ni eeyan mọkanla ti wọn tun pade iku ojiji nibi akọlu awọn janduku afẹmisofo ti wọn ya wọ Abule Ancha, to wa ni ijọba ibilẹ Bassa, nipinlẹ Plateau. Bẹẹ naa ni wọn dana sun ọpọ ile nibẹ.
Oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe awọn afẹmiṣofo naa ti wọn pọ niye ya wọ abule naa, ti wọn si dana sun un un lasiko ti awọn olugbe ibẹ n sun lọwọ.
Nibi ti awọn eeyan yii ti n sa asala fun ẹmi wọn latari ina ti wọn sọ si awọn ile to wa nibẹ ni wọn ti n ko sọwọ awọn afẹmisofo to ti lugọ de wọn naa. Bi wọn si ti n jade ni wọn n mu wọn balẹ. Nigba ti oloju yoo fi ṣẹ ẹ, eeyan bii mọkanla lo ti jẹ Ọlọrun nipe.
Agbẹnusọ fun ajọ kan to n mojuto eto aabo nipinlẹ naa ti wọn n pe ni ‘Operation Save Haven, Mejọ Ishaku Takwa, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni loru Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lawọn gba ipe pajawiri pe awọn afẹmiṣofo ti ya wọ Abule Ancha, nijọba ibilẹ Basaa. Loju-ẹsẹ lawọn si ti ko awọn eeyan awọn, ti awọn lọ sibẹ, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn janduku naa ti sa lọ.
O waa kẹdun pẹlu awọn eeyan abule naa ati awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba yii.