Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn agbebọn ti ṣeku pa olori awọn Fulani, Alhaji Alhaji Sheidu Madawaki, labule Obuh Ruga, Oro Ago, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ni Huusu ipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an abọ, ọjọ Aiku, Sunnde, ọsẹ yii, ni awọn agbebọn ọhun ya wọ ileegbe rẹ to wa labule Obuh Ruga, Oro Ago, ti i ṣe ilu Igbakeji gomina ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Kayọde Alabi, ti wọn si yinbọn lu olori awọn Fulani naa, oju-ẹsẹ lo ku.
Iwadii fihan pe oloogbe ọhun ṣe abẹwo si ọfiisi ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, to si n pe fun bi alaafia yoo ṣe maa jọba ni agbegbe naa. Bakan naa lo beere fun aabo to peye lori awọn ti yoo maa ṣofofo awọn ọdaran, ti ajọ naa si fi i lọkan balẹ pe aabo to daju wa fun awọn to ba tu aṣiri awọn ọdaran ni agbegbe ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ni kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, ti sọ pe ki iwadii o bẹrẹ lori iṣẹlẹ buruku ọhun.