Nitori bi eto aabo to dẹnukọlẹ, ijọba ṣepade pẹlu awọn adari Fulani ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ṣepade pẹlu awọn adari Fulani nipinlẹ naa nitori eto aabo to dẹnukọlẹ, ati ki alaafia le maa jọba.

Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni Abdulrazak ṣepade pọ pẹlu adari ẹya Fulani latari gbedeke ọjọ ti ẹkun Guusu Naijiria fun awọn Fulani darandaran lori didaranjẹ ni gbangba ni ẹkun naa, ti awọn Fulani ọhun si n ya wọ ipinlẹ Kwara bo ṣe wu wọn. Gomina ti waa sọ fun awọn adari Fulani naa lati ri i daju pe wọn wa wọrọkọ fi sada lori bi awọn darandaran ọhun ṣe n ya wọ ipinlẹ Kwara bo ṣe wu wọn, to si jẹ ewu gidi fun aabo ipinlẹ ọhun.

Abdulrazaq tẹsiwaju pe awọn Fulani darandaran yii, pẹlu awọn agbẹ gbọdọ mọ bi wọn yoo ṣe maa gbe pọ ni alaafia ati ifọkanbalẹ, tori pe ipade naa ko sẹyin ipo ti eto aabo wa ati awọn ohun to n ṣẹlẹ ni awọn agbegbe ni ipinlẹ Kwara lọwọ lọwọ. Bakan naa ni gomina ni oniruuru eto ni ijọba Kwara ti gbe kalẹ lati fi ṣe ilanilọyẹ lori bi Fulani ati agbẹ yoo ṣe maa gbe pọ lai si gbọnmi si i, omi o to o laarin wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Tuesday Assayomo, to sọrọ nibi ipade ọhun sọ pe awọn pe ipade yii lati rọ awọn Fulani ati agbẹ ki wọn fọwọsowọpọ laarin ara wọn gẹgẹ bii ijọba ati awọn ẹsọ alaabo ṣe n gbiyanju lati ri i daju pe aabo to duroo re rẹsẹ walẹ ni ipinlẹ Kwara.

 

Aarẹ awọn agba Fulani, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Alhaji Ahmed Magaji, ti oun naa sọrọ nibi ipade ọhun sọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ bo ṣe jẹ pe wọn sọ awọn Fulani ni orukọ buruku, ati pe lati ọdun pipẹ ni awọn eniyan awujọ ti n dẹyẹ si ẹya Fulani, kọda wọn o jẹ ki ẹya naa jẹ anfaani eto ẹkọ to jiire lorile-ede yii.

Leave a Reply