Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ifọkanbalẹ lawọn ajinigbe marun-un kan fi ji Aafaa Abduljẹlii ati ikeji ẹ, Aafaa Ilyas Jamiu, gbe l’Ayetoro, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, nitori bi wọn ṣe gbe wọn si mọto tan, wọn ko lọ o, niṣe ni wọn wọ kiṣinni iyawo Jẹlili, wọn si farabalẹ pari ọbẹ ti obinrin naa se, ẹba ni wọn fọbẹ naa jẹ.
Ijọba ibilẹ Ariwa Yewa niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ lalẹ ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila yii.
Ohun to tilẹ buru ni pe lẹyin tawọn ajinigbe ti wọn dihamọra ogun naa pitu ọwọ wọn tan, miliọnu lọna mẹẹẹdogun Naira ( 15m) ni wọn lawọn fẹẹ gba lọwọ ẹbi awọn aafaa meji naa.
Alaye ti ẹgbọn Aafaa Jẹlili, iyẹn Ọgbẹni Ibrahim Hussein, ṣe ni pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa lawọn ajinigbe marun-un naa de tijatija.
O ni aburo oun ati aafaa keji ṣẹṣẹ n de lati waasi ti wọn lọ ni. Koda, o ni bi wọn ṣe n sọkalẹ ninu okọ Toyota Highlander ti Aafaa Jẹlili ṣẹṣẹ ra loṣu meji sẹyin lawọn agbebọn to ji wọn gbe naa bo wọn, ni wọn ba gbe wọn.
Ọkunrin naa sọ pe bi wọn ṣe mu aburo oun ati aafaa keji tan, niṣe ni wọn wọle lọọ ba awọn araale yooku, wọn bẹrẹ si i gba foonu wọn. Lẹyin naa lo ni wọn wọ ile idana iyawo aafaa lọ, wọn jokoo ti ẹba to wa nibẹ pẹlu ọbẹ ẹran ti iyawo naa se, wọn si fi gbogbo ẹ jẹ tan ki wọn too ṣina si mọto, ti wọn gbe awọn aafaa mejeeji lọ.
Lẹyin ti wọn gbe wọn lọ tan ni wọn bẹrẹ si i pe awọn eeyan wọn pe miliọnu mẹẹẹdogun lowo itusilẹ awọn aafaa yii bi wọn ba tun fẹẹ foju kan wọn laye.
Ṣugbọn DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, sọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ yii, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ lori bawọn yoo ṣe ri awọn aafaa mejeeji gba pada.
Oyeyẹmi sọ pe awọn ọlọpaa pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ atawọn alaabo gbogbo ti wa ninu igbo wayi, ti wọn n wa awọn ajinigbe yii atawọn to ji wọn gbe.
O ni laipẹ yii lawọn mu ajinigbe meji n’Ijẹbu-Ode, bẹẹ naa lawọn yoo mu awọn eleyii naa laipẹ, awọn yoo si gba awọn ti wọn ko sigbekun silẹ.