Faith Adebọla
Awọn afẹmiṣofo ti wọn jiiyan gbe lagbegbe Oke-Ọya ti sọko ibanujẹ sidile ọkan lara awọn aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Ibrahim Aminu Kurami, niṣe ni wọn palẹ iyawo ati meji lara awọn ọmọ rẹ mọ lagbegbe Bakori, nipinlẹ Katsina, ti wọn si ji wọn gbe lọjọ Abamẹta, Satide.
Ba a ṣe gbọ, ori lo ko Ọnarebu Kurami funra ẹ yọ, wọn ni gẹlẹ tiṣẹlẹ naa waye tawọn agbebọn naa ti kuro tan lo dari de lati ode to lọ. Ọnarebu Kurami lo n ṣoju ẹkun idibo Bakori nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Katsina.
Ẹnikan to ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe ọkada ati ọkọ ayọkẹlẹ lawọn agbebọn naa gbe wa, o si jọ pe wọn diidi waa ṣọṣẹ naa ni, nitori taara ti wọn de, ilẹ aṣofin naa ni wọn fori le, ko si pẹ ti wọn ji awọn eeyan rẹ ọhun gbe.
“Ba a ṣe pari irun kiki to gbẹyin lalẹ (Irun Ishaa’i) niṣe la bẹrẹ si si gburoo ibọn laarin ilu, ka too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn agbebọn naa ti pin ara wọn bii ẹni pagbo ijo nla, awọn kan si i lọọ duro sawọn ibi pataki laarin ilu naa, boya nitori kawọn araalu ma le di wọn lọwọ tabi gbeja ko wọn ni.
Niṣe ni wọn lọọ taara sile Aṣofin Kurami, ti wọn si ji iyawo ẹ ati ọmọ meji gbe, inu mọto ti wọn gbe wa ni wọn fi gbe wọn lọ.”
Lasiko iṣẹlẹ aburu ọhun, wọn ṣe ẹni kan leṣe, Ọgbẹni AbdulKadir Ubaidu, diẹ lo ku ki wọn pa a, nigba tọkunrin naa ko si wọn lọwọ lojiji, ti ko si tete mọ’ru ẹni ti wọn jẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn lawọn ti bẹrẹ igbesẹ to yẹ lori ẹ lati doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe.