Awọn agbebọn ji kabiyesi olori ati dẹrẹba rẹ gbe lọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọrọ ti gbogbo eeyan n pe ni ọwẹ ti n laro ninu bayii o, atẹgun to ka aṣọ ni yara lọrọ naa da bayii, ki ẹni to wọ tiẹ sọrun ma ṣafira pẹlu bi awọn agbebọn ṣe ji ọba alaye kan, Abdulrahaman Ifabiyi, Onire tilu Ọwa-Onire, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, ati olori rẹ pẹlu dẹrẹba wọn gbe lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita niluu Ilọrin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni iroyin ti tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ nipa bi awọn agbebọn kan se ji ọba alaye naa, iyawo, ati dẹrẹba rẹ gbe lọjọ Abamẹta. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣalaye ibi ti  ọba alaye naa atiyawo rẹ n lọ tabi ti wọn ti n bọ ti wọn fi ji wọn gbe.

Ajayi sọ pe awọn agbofinro pẹlu ajọṣepọ ẹṣọ alaabo fijilante ti doola ẹmi iyawo kabiyesi, ti wọn si n ṣapa wọn lati doola ori-ade naa kuro lakata awọn ajinigbe. Bẹẹ lo ni ọwọ ti tẹ meji ninu awọn ajinigbe naa, iṣẹ si n lọ lati ri aọn to ku mu.

O tẹsiwaju pe iyawo kabiyesi ti dara pọ mọ awọn mọlẹbi rẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Paul Odama, si ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn agbebọn yooku lawaari, ki wọn doola kabiyesi, ki wọn si fi awọn agbebọn naa jofin.

Leave a Reply