Awọn agbebọn ji oṣiṣẹ-fẹyinti gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Oṣiṣẹ-fẹyinti kan to ti fẹyinti nileeṣẹ eto ilera nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Israel Bamisaye, ni awọn ajinigbe kan ti ji gbe.
Bamisaye, ni wọn ni awọn ajinigbe kan ti wọn to meje ji gbe pẹlu ibọn ni oju ọna oko to wa ni (Ẹrọ Dam), ni Ọrin-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Osin.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ to ba ALAROYE sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ sọ pe ninu oko ọkunrin naa ni wọn ti ji i gbe ni deede aago mẹrin aabọ irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, nigba to n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko naa.
Ni kete ti wọn ji i gbe ni awọn araalu naa jade lati fi ẹhonu han ta ko bi awọn ajinigbe ṣe n ji awọn eeyan ilu naa gbe, ati bi ijọba yoo ṣe pese aabo lori awọn araalu naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ajinigbe naa ti kọkọ ṣe akọlu si ọkunrin kan ti orukọ rẹ njẹ Ojo niluu naa.
O sọ pe bi wọn ṣe ba a ninu oko rẹ ni wọn beere boya o mọ ibi ti awọn oṣiṣẹ ti wọn jẹ oyinbo ti wọn n ṣiṣẹ ninu oko naa wa, ṣugbọn o da wọn loun pe oun ko mọ ibi ti wọn wa. Ọkunrin naa ni alejo ni oun niluu naa.

Lọgan ni wọn paṣẹ fun un pe ko dọbale, ti wọn si sayẹwo inu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ to wa ninu oko naa, ti wọn si tun ko owo to to bii ẹgbẹrun mẹrin ataabọ (N4,500) to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa lọ.
Awọn ajinigbe naa yinbọn soke, ki wọn too gbe oṣiṣẹ-fẹyinti naa lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ijinigbe naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ni ẹrọ ilewọ rẹ ko sọrọ, ṣugbọn ọga ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni awọn ẹṣọ loriṣiiriṣii ti wa ni agbegbe naa lati gba oṣiṣẹ-fẹyinti ti wọn ji gbe naa silẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: