Awọn agbebọn ji olori adugbo atawọn mẹta mi-in gbe l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Oniku ti Iku, niluu Ikarẹ Akoko, Oloye Giga Mukaila Bello, atawọn mẹta mi-in, lawọn agbebọn kan tun ji gbe lagbegbe Ọwọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Awọn ti wọn ji gbe pẹlu baalẹ ọhun la ti ri oloye obinrin kan niluu Ikarẹ, Yeye Gbafinro, oloye ẹgbẹ APC kan n’Ikarẹ Akoko, Ọnarebu Adeniran Adeyẹmọ, ati ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Basiru Adekilẹ.

 

Awọn eeyan ọhun la gbọ pe wọn ji gbe lagbegbe kan ti wọn n pe ni Agọ Paanu, nitosi Ọwọ, eyi to wa loju ọna marosẹ Ọwọ si Ikarẹ.

 

Ilu Akurẹ ni wọn lawọn eeyan naa ti n bọ lalẹ ọjọ iṣẹlẹ ọhun ti wọn si n pada si ibugbe wọn ni Ikarẹ Akoko, ki awọn agbebọn too da wọn lọna, ti wọn si ko wọn wọnu igbo lọ.

Dẹrẹba ọkọ ti wọn wọ nikan ni wọn lori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun bo tilẹ jẹ pe ṣe ni wọn kun awakọ naa ladaa yannayanna, to si wa ni ile-iwosan kan, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Ọkan ninu ẹbi awọn ti wọn ji gbe ọhun lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin, o ni ko ti i si ohunkohun ti awọn si gbọ lati ọdọ awọn agbebọn to ji awọn eeyan naa gbe.

 

Ileeẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo naa ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atejade kan ti wọn fi sita laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Wọn ni ori ere lawọn agbebọn naa ti ina ibọn bo ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla tawọn eeyan ọhun wa ninu rẹ, ti ọkọ naa si duro tipatipa lẹyin ti ọta ibọn ti ba awakọ wọn lori.

 

Ileeẹ ọlọpaa ni awọn mẹrẹẹrin to wa ninu ọkọ naa lawọn ajinigbe ko wọnu igbo lọ nigba ti wọn fi awakọ ti ibọn ba nikan silẹ ninu agbara ẹjẹ.

 

Wọn fidi rẹ mulẹ pe ara dẹrẹba naa ti n ya diẹdiẹ ni ọsibitu to ti n gba itọju, awọn ọlọpaa, ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante si ti fọn sinu igbo lati lepa awọn ọdaran ọhun titi tọwọ yoo fi tẹ wọn.

Leave a Reply