Awọn agbebọn ji tọkọ-tiyawo gbe lasiko ti wọn n bọ lati iṣọ-oru

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ wiwa awọn tọkọ-tiyawo kan ti awọn agbebọn ji gbe nipinlẹ Ọṣun lopin ọsẹ to kọja.

Ṣọọṣi la gbọ pe awọn eeyan naa ti n bọ ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lẹyin ti wọn pari iṣọ-oru.

Bi wọn ṣe de agbegbe Kelebe, loju ọna Iragbiji si Oṣogbo, ni wọn kan igi nla kan ti awọn agbebọn naa gbe di oju ọna. Ṣugbọn awọn eeyan naa ko mọ pe awọn oniṣẹ ibi naa lo gbe igi ọhun dina.

Lasiko ti wọn rọra n rin nitori igi to wa ni oju ọna naa pẹlu ọkada wọn lawọn agbebọn naa jade, ti wọn si ko awọn mejeeji wọnu igbo lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn ọdẹ atawọn ọlọpaa pẹlu awọn agbofinro mi-in ti fọn sinu igbo to wa layiika naa lati gba awọn tọkọ-taya naa silẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ ọhun  mulẹ, o si fi da awọn araalu loju pe laipẹ ni ọwọ yoo tẹ awọn amookunṣika naa, ti awọn yoo si gba awọn ti wọn ji gbe silẹ.

Leave a Reply