Awọn agbebọn kọ lu awọn oloye ilu Ọwọ, wọn pa ẹni kan, wọn ṣe ẹlomi-in leṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn ọdọ ni wọn jade lati fẹhonu han ta ko iku Oloye Giga Tunde Ilọri Elewere, tawọn agbebọn kan yinbọn pa lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye, lo gbe awọn oloye rẹ kan dide lati lọọ yanju awuyewuye to wa lori ọrọ ilẹ tawọn eeyan kan ati Oloye Elewere n fa mọ ara wọn lọwọ.

Ibi ilẹ naa ni wọn ti n bọ nigba tawọn janduku kan deedee yọ si wọn, wọn yinbọn pa Oloye Elewere loju-ẹsẹ, bẹẹ ni wọn tun ṣe oloye mi-in leṣe.

Oloye keji ti wọn ṣe leṣe la gbọ pe o ṣi wa nileewosan kan ta a forukọ bo laṣiiri to ti n gba itọju.

Ohun to bi awọn ọdọ ọhun ninu ree ti wọn fi tu yaayaa jade la ti fẹhonu wọn han lori iṣẹlẹ naa.

Ọjọ iṣẹlẹ ọhun gan-an ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti gbe Igbakeji rẹ, Ọnarebu Lucky Aiyedatiwa, dide lati lọọ ba Ọlọwọ kẹdun iku ọkan ninu awọn ijoye rẹ.

Lara awọn to ba igbakeji gomina ọhun kọwọọrin lọ siluu Ọwọ ni Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Olugbenga Ale, Oludamọran agba fun gomina lori akanṣe iṣẹ, Dare Aragbaye, Oluranlọwọ pataki fun gomina lori ọrọ eto aabo, Alaaji Jimọh Dojumọ, ati oludari ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ.

Nigba to n jiṣẹ gomina fun Ọlọwọ, Ọnarebu Aiyedatiwa ba awọn eeyan ilu Ọwọ ati gbogbo mọlẹbi oloye ọhun kẹdun lori ọfọ nla to ṣe wọn.

Akeredolu ṣeleri lati ṣawari awọn oniṣẹ-ibi ọhun lọnakọna, ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin.

Ọba Ajibade ninu ọrọ tirẹ dupẹ lọwọ gomina atawọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ fun imọlara ti wọn fihan lori iṣẹlẹ naa lai fi akoko falẹ.

Ọlọwọ ni Oloye Elewere funra rẹ lo kọkọ waa fẹjọ sun laafin lori ọrọ ilẹ ti oun ati idile kan n fa mọ ara wọn lọwọ.

O ni loju-ẹsẹ loun ti gbe igbimọ kan dide lati ba wọn yanju aawọ ọhun, to si jẹ pe Oloye Elewere lawọn igbimọ naa da lare.

Lẹyin eyi lo ni oun tun gbe igbimọ mi-in dide l’Ọjọruu, Wẹsidee, lati pada lọ sori ilẹ ọhun fun atunyẹwo ki alaafia le jọba patapata.

Ọlọwọ ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba ti ẹnikan deedee pe oun sori ago pe ki oun pe awọn ijoye oun wo, ẹni ọhun ni oun gbọ funrinfinrin pe awọn janduku kan ṣe akọlu si awọn oloye ti oun ran jade.

Ọba alaye ọhun bẹ gomina ko tete mu ileri rẹ ṣẹ nipa ṣiṣe awari awọn janduku agbebọn naa ni gbogbo ọna, ki wọn le foju wina ofin lori iṣẹ ibi ti wọn ṣe.

 

Leave a Reply