Eeyan meji ku ninu ijamba tirela ati kẹkẹ NAPEP n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Niṣe lawọn eeyan kawọ leri nigba ti wọn ri bi tirela kan ṣe tẹ awakẹkẹ NAPEP kan pa n’Ibadan laaarọỌjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Laduugbo Alakia, n’Ibadan, niṣẹlẹ ọhun ti waye ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ Ọjọbọ.

Kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ta a mọ si kẹkẹ NAPEP tabi kẹkẹ Maruwa mẹta ni mọto nla naa kọ lu, to si pa ọkan ninu awọn awakẹkẹ naa lẹsẹkẹsẹ

Latẹyin la gbọ pe mọto nla ọhun ti kọ lu awọn kẹkẹ mẹtẹẹta naa, to si run wọn jegejege.

Wọn lawọn to wa ninu awọn kẹkẹ naa yara bẹ jade kuro ninu kẹkẹ wọn lati sa asala fun ẹmi wọn, ṣugbọn nnkan ko ṣẹnuure fun ọkan ninu wọn nitori nibi to ṣubu si lọkọ nla naa ti lọọ gun un lori, to si tẹ ẹ pa loju-ẹsẹ.

Awọn ti ṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn fidi ẹ mulẹ pe bi awakọ naa ṣe ri i pe oun ti paayan lo ti ki are mọlẹ, to bẹrẹ si i sa lọ. N lawọn ọdọ to wa laduugbo naa ba gba ya a.

Nibi to ti n sa lọ lo tun ti lọọ kọ lu ọmọde kan to n lọ sileewe jẹẹjẹ ẹ, to si ṣe bẹẹ pa ọmọọleewe naa.

Inu teṣan ọlọpaa to wa l’Ẹgbẹda, n’Ibadan, lawọn kẹkẹ to bajẹ naa wa bayii. Awọn awakọ agbegbe naa la gbọ pe wọn gbe wọn lọ sibẹ.

Leave a Reply