Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lasiko tawọn janduku lọọ kọ lu teṣan ọlọpaa Ẹlẹrinla, eyi to wa lagbegbe ibudokọ Ileṣa, niluu Akurẹ, loru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn pa ọlọpaa kan, Temenu Boluwaji.
Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, fi ṣọwọ si awọn oniroyin lo ti ṣalaye pe lojiji lawọn janduku ọhun ya bo wọn ni nnkan bii aago kan oru ọjọ naa, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.
Alukoro ṣalaye pe awọn agbofinro to wa lẹnu iṣẹ nigba naa gbiyanju lati doju ija nla kọ wọn, eyi ti ko jẹ ki wọn lanfaani ati raaye wọ inu tesan ọhun gẹgẹ bii ifẹ ọkan wọn.
Ọdunlami ni aarin asiko tawọn ẹṣọ alaabo atawọn to waa ṣe akọlu naa n yinbọn fun ara wọn ni ọlọpaa ọhun ti fara gbọta, ti awọn ẹgbẹ rẹ si sare gbe e digba digba lọ sile-iwosan lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti ọkunrin naa pada ku ki wọn too de ọsibitu.
Ohun ta a gbọ ni pe kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Oyeyẹmi Adeṣọye Oyediran, ti paṣẹ fun ẹka ileeṣẹ wọn to n ṣe iwadii iwa ọdaran lati bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ naa lẹyẹ-o-ṣọka, ki wọn si ri i daju pe wọn mu awọn ọdaran ọhun kiakia.
Bakan naa ni agbẹnusọ awọn ọlọpaa ọhun tun rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati fọkan balẹ, ki wọn ma si ṣe bẹru ohunkohun nitori pe ko sibi tawọn ọdaran le fara pamọ si tọwọ ko ni i tẹ wọn.