A-gbọ-sọgba-nu ni iku ẹṣọ Amọtekun kan, Suleiman Quadri, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn tawọn agbebọn pa niluu Fiditi, nipinlẹ Ọyọ, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn kan ti wọn to bii mọkanla ti wọn dihamọra ni wọn jinbọn pa ẹṣọ Amọtẹkun yii lasiko ti o n tẹle awọn oṣiṣẹ oko nla kan lọ si oko wọn to wa ni Fiditi lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.
Awọn meji la gbọ pe wọn n ṣọ awọn oṣiṣẹ yii lọ sinu oko wọn, Amoo Yisau ati Quadri ti wọn pa yii.
A gbọ pe bi wọn ṣe ri awọn ẹṣọ Amọtẹkun yii ni wọn dana ibọn bo wọn, ti wọn si n yinbọn naa lakọlakọ lu wọn. Ibọn naa lo ṣeku pa Quadri loju-ẹsẹ, nigba ti Yisau fara pa ni tiẹ. Ọsibitu Jẹnẹra to wa niluu Ọyọ ni wọn sare gbe ọkunrin naa lọ fun itọju.
Ọga ẹṣọ Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ ni wọn ti simku ọkunrin naa nilana Musulumi.