Awọn agbebọn pa eeyan kan, wọn si ji ọpọlọpọ gbe loju-ọna Oṣogbo si Ibokun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọwọlọwọ bayii, agbarijọpọ awọn ikọ alaabo nipinlẹ Ọṣun ti wa ninu igbo nitosi abule kan ti wọn n pe ni Ẹgbẹda, loju-ọna Oṣogbo si Obokun, lati doola awọn arinrin-ajo ti awọn ajinigbe ji lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Nnkan bii aago meje aabọ si mẹjọ alẹ la gbọ pe awọn ajinigbe ti ẹnikẹni ko ti i mọ iye wọn bayii ya bọ soju popo pẹlu ibọn AK 47 loriṣiiriṣii, ti wọn si da awọn arinrin-ajo to n kọja lọna.

A gbọ pe awọn agbebọn naa pa ẹni kan lara wọn, ko too di pe wọn ko awọn to ku wọnu igbo lọ.

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Kọmureedi Amitolu Shittu, ṣalaye pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn ti kọja sibẹ, o ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ri awọn eeyan naa gba silẹ.

Leave a Reply