Awọn agbebọn pa oṣiṣẹ ẹsọ oju popo l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹsọ oju popo to wa niluu Ondo, Omiwọye Sunday, lawọn janduku kan ṣeku pa lalẹ ọjọ Aiku, Sunday, ọsẹ ta a wa yii.

Oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo ọhun la gbọ pe wọn ṣe akọlu si níbi to ti n gbeja awọn eeyan kan lagbegbe Agbala, Elewuro, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnu Abilekọ Bummi Sunday to jẹ iyawo oloogbe pe niṣe lawọn jọ ṣere jade lalẹ ọjọ naa lati lọọ ki ọrẹ rẹ kan to n gbe laduugbo Agbala.

Bo ṣe de ẹnu geeti ile ti wọn n lọ lo duro to si fẹẹ gbe ọkada rẹ pamọ sibi kan lo ri awọn eeyan kan ti wọn sare waa ba a, ko le gba wọn silẹ lọwọ awọn eeyan kan to n le wọn.

O ni ibi ti awọn ti n wo awọn eeyan naa tiyanu tiyanu lawọn meji kan ti gun ọkada de, ti wọn si n lu awọn ọkunrin to n sa kiri naa mọ ọkọ oun lara.

Kiakia ni iyawo ti sa wọle ni tirẹ, ṣugbọn ti ọkọ rẹ duro gbọningbọnin lati koju awọn agbebọn ọhun, to si n gbiyanju ati gba awọn eeyan ti wọn n lu naa silẹ lọwọ wọn.

Abilekọ Sunday ni awọn n gbọ nigba tawọn agbebọn naa n kíkọ fun ọkọ oun pe ko ma ṣe da si ohun ti ko kan an nitori pe awọn ko ba tìrẹ wa.

O ni ko pẹ rara lẹyin ti oun sa wọle tan loun deedee gburoo ibọn to dun, jijade ti yoo si tun pada jade sita lo ba ọkọ rẹ ninu agbara ẹjẹ ti wọn ti yinbọn lu u.

Awọn agbebọn ọhun lo ni wọn gba ẹrọ ilewọ ati kọkọrọ ọkada rẹ lọwọ rẹ ki wọn too bẹ sori ọkada tiwọn, tí wọn si sa lọ tefetefe.

Ohun ta a gbọ ni pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ bẹẹ n waye lagbegbe naa, gbogbo igba ni wọn lawọn adigunjale maa n yọ wọn lẹnu, leyii to ṣokunfa bi awọn onile kan ṣe n fi ile wọn silẹ, ti wọn si n sa kuro lọ si ibomiran.

Wọn ti gbe oku Sunday lọ si mọṣuari ile-iwosan ìjọba to wa niluu Ondo, nibi ti wọn tọju rẹ pamọ si lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Nigba ta a kan si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, lori ago, ohun to sọ fun wa ni pe oun ko ti i gbọ ohunkohun nipa rẹ.

Leave a Reply