Stephen Ajagbe, Ilorin
Ariwọ ẹkun ati ọfọ lo gba agboole Magaji ilu Rẹkẹ, nijọba ibilẹ Afọn, nipinlẹ Kwara, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nitori bawọn agbebọn kan ṣe kọ lu ile naa, ti wọn si gbẹmi ọmọ rẹ ọkunrin. Ọpọlọpọ araalu naa ni wọn pe jọ sile Magaji ọhun lati ba a kẹdun iku ọmọ rẹ.
ALAROYE gbọ pe arin oru ọjọ Aiku, Sannde, lawọn agbebọn naa waa ka ọkunrin naa mọle. Ori ibusun ninu yara rẹ ni wọn ti ba a pẹlu awọtẹlẹ to wọ sun, ibẹ gan-an ni wọn pa a si.
Nigba tilẹ ọjọ keji, Mọnde, yoo si mọ, inu agbara ẹjẹ ni wọn ti ba ọkunrin naa, eyi mu ki ariwo ẹkun sọ lagbala wọn.
Alukoro ileeṣẹ NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe nnkan bii aago mẹfa aarọ niroyin iṣẹlẹ naa to awọn leti.
O ni ni nnkan bii aago meji oru lawọn ọdaran naa lọọ ka a mọle pẹlu ohun ija oloro, ti wọn si da ẹmi rẹ legbodo lai ni idi kan pato.
O ni awọn ọlọpaa to wa niluu Afọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ silewosan ijọba fun ayẹwo lati fidii iru iku to pa a mulẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun ti oloogbe naa pẹlu awọn to ṣeku pa a n fa mọ ara wọn lọwọ, iwadii fi han pe alagidi eeyan ni ọkunrin naa, ki i gbọ, bẹẹ ni ki i gba.
Iṣẹlẹ ọhun da ẹru silẹ laarin ilu Rẹkẹ, titi di bi a ti ṣe n kọ iroyin yii lawọn araalu ṣi n sọrọ iku ọkunrin naa.