Awọn agbebọn tan Alawiye atawọn oṣiṣẹ rẹ wọnu oko l’Ọgbẹṣẹ, ni wọn ba ji wọn gbe lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di ba a ṣe n sọrọ yii ni wọn ṣi n wa ọkunrin agbẹ kan, Adebayọ Alawiye atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹrin, ti wọn ji gbe ninu oko wọn niluu Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe Adebayọ lo gba ipe ojiji kan lori foonu rẹ lalẹ ọjọ naa, ti onitọhun ni ko tete maa bọ sinu oko rẹ lati waa pa ina to ti fẹẹ jo gbogbo oko naa run.

Loju-ẹsẹ lọkunrin naa ti pe awọn oṣiṣẹ rẹ bii mẹsan-an jọ, ti wọn si jọ mori le ọna oko naa, ṣe ko sẹni ti yoo gbọ iru ipe ijaya bẹẹ ti ara aje ko nii ta a.

Awọn agbebọn naa la gbọ pe wọn fun wọn laaye ki wọn fi kọja sinu oko lọhun-un ki wọn too jade nibi ti wọn fara pamọ si, ti wọn si ko gbobgo wọn wọnu igbo lọ.

Marun-un ninu awọn mẹwaa ti wọn ji gbe ọhun la gbọ pe wọn ti tu silẹ lẹyin ọjọ diẹ ti iṣẹlẹ naa waye, nigba ti Adebayọ to jẹ ọga wọn atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹrin ṣi wa ninu igbekun awọn ajinigbe titi di asiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Ibẹrẹ ọsẹ ta a wa yii ni wọn lawọn onisẹẹbi naa kan si awọn ẹbi baba agbẹ ọhun, ti wọn si ni wọn gbọdọ waa san ọgọrun-un miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ awọn marun-un to si wa ni ikawọ wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lori bi awọn ti wọn ji gbe ọhun yoo ṣe ri idande laipẹ.

Leave a Reply