Awọn agbebọn ti tu Biṣọọbu Aderọgba atiyawo rẹ silẹ lahaamọ

Jọkẹ Amọri

Ko ti i ṣeni to mọ boya wọn san miliọnu lọna aadọta ti wọn beere fun, ṣugbọn ohun ti a le fidi rẹ mulẹ ni pe awọn ajinigbe ti tu Biṣọọbu Aderọgba ti ijọ Angican, ẹkun Jẹbba, ati iyawo rẹ pẹlu dẹrẹba wọn ti wọn ji gbe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii silẹ.
Biṣọọbu Ẹkun Omu-Aran, Rt. Rev. Festus Ṣobankẹ, lo sọrọ naa fun tẹlifiṣan ACNN to gbe iroyin yii jade, to si fidi rẹ mulẹ pe wọn ti di riri.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa yii, ni wọn ji awọn tọkọ-titawo yii pẹlu dẹrẹba wọn gbe niluu Ogbomọṣọ, nigba ti wọn n bọ lati ijọ naa to wa ni Ẹkun Yewa, ti wọn ti lọọ ṣepade, ti wọn si n pada siluu Jẹbaa.
Ilu Ogbomọṣọ ni wọn ti dabuu wọn lasiko ti ọkọ ti wọn gbe lọ yọnu, ti wọn si n gbiyanju lati wa ojutuu si i.
Lẹyin ti wọn ji wọn gbe lawọn agbebọn naa beere fun miliọnu lọna aadọta Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.
Ṣugbọn ko sẹni to le sọ boya wọn sanwo naa tabi wọn

Leave a Reply