Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni awọn agbebọn to dihamọra pẹlu ibọn ati awọn ohun ija oloro tun ji agbẹ kan, Alaaji Ẹlẹfọ, gbe lọ ninu oko rẹ to wa niluu Ballah, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara.
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni awọn ajinigbe ọhun ya bo oko arakunrin naa, ti wọn si n rọjo ibọn kikankikan. Lasiko naa ni wọn ji agbẹ yii gbe lọ patapata.
Awọn olugbe agbegbe naa sọ pe ṣe ni awọn gbọ iro ibọn to n dun leralera, ti ibẹrubojo si gba gbogbo ọkan awọn olugbe agbegbe naa. Titi di igba ta a n ko iroyin yii jọ, wọn o ti i gbọ mo ko o Alaaji Ẹlẹfọ ti wọn ji gbe, ṣugbọn awọn ẹṣọ alaabo Vigilante ati ọlọpaa ti bẹrẹ si i lepa awọn ajinigbe ọhun.