Awọn agbebọn to ji aafa at’ọmọ ẹ n’Ilọrin n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn agbebọn to ji Aafa Sọfiu, ọmọ rẹ ati ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Aliyu, gbe lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara  ti n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni awọn agbebọn naa ji awọn mẹtẹẹta gbe lọ nileegbe wọn lopopona Jẹbba, Oko-Olowo, niluu Ilọrin, lẹyin ti wọn yọ irin oju ferese ni wọn raaye wọle, ti wọn si tun fi ọta ibọn da ọgbẹ sara ọmọ Aafa Sọfiu kan ti orukọ rẹ n jẹ Fasasi.

Baba aafa ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, Imam Amolegbe, ti agbegbe Dada, Okelele, Ilorin, sọ fun awọn oniroyin pe awọn ajinigbe naa ro pe Fasasi ti ku nigba ti wọn yinbọn mọ ọn ni wọn ṣe fi i silẹ, sugbọn awọn mọlẹbi ti gbe e lọ si ileewosan aladaani kan, nibi to ti n gba itọju bayii.

O fi kun un pe wọn ti bẹ awọn ajinigbe naa ki wọn gba miliọnu mẹwaa Naira, bo tilẹ jẹ pe ko si owo ọhun nilẹ bayii. O rọ ijọba Kwara atawọn ẹlẹyinju aanu ki wọn dide iranlọwọ, ki wọn le tu eeyan wọn yii silẹ lahaamọ awọn ajinigbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi meji lori iṣẹẹ ọhun, ati pe awọn ti n sa gbogbo ipa lati doola awọn aafa naa.

Leave a Reply