Awọn agbebọn tu ijokoo igbimọ alaṣẹ Kwara Poly ka n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn janduku agbebọn ti wọn fura si gẹgẹ bii ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun, ya bo ijokoo igbimọ alaṣẹ to n gbẹjọ lori awọn akẹkọọ to ṣe magomago lakooko idanwo, ti wọn si tu ijokoo naa ka, ninu ọgba ile ẹkọ ọhun to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe akọlu naa waye lasiko ti igbimọ naa jokoo, ti wọn ni ki awọn akẹkọọ ti wọn ṣe magomago lakooko idanwo waa sọ ohun ti wọn ri ti wọn fi gbeegun lakooko idanwo naa, sugbọn awọn agbebọn dabaru eto naa, ti erongba wọn si fori sanpọn.

Ẹni tọrọ naa ṣoju rẹ to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe lojiiji lawọn agbebọn naa ya bo inu ọgba ile-ẹkọ naa, ti wọn si n yinbọn soke, eyi lo da ibẹru-bojo silẹ, ti gbogbo awọn akẹkọọ at’olukọ si sa asala fun ẹmi wọn.

Gbogbo ẹrọ ibanisọrọ awọn igbimọ naa ni wọn gba patapata. Ṣa o, ohun gbogbo ti pada bọ sipo ni akoko ti a n ko iroyin yii jọ.

 

Leave a Reply