Faith Adebọla
Iduro ko si, ibẹrẹ ko si mọ, fun ọpọ araalu lagbegbe Oke-Ọya ilẹ wa, pẹlu bi ẹlẹkọ ọrun ṣe n polowo gidigidi lagbegbe naa, tawọn agbebọn si n fojoojumọ ji awọn ọmọleewe ati araalu rẹpẹtẹ gbe wọgbo.
Oru mọju Ọjọbọ, Tọsidee yii, la gbọ pe awọn janduku afẹmiṣofo naa gbe iṣe wọn de, wọn ya bo ileto Ungwan Matari, to wa lagbegbe Sabon Tasha, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lori bẹẹdi wọn, ti wọn n ko wọn sori ọkada ti wọn gbe wa, wọn si ji wọn gbe lọ raurau.
Wọn ni ọna to gba odo Romi, nitosi Gbagyi, ni wọn gba wa ni nnkan bii aago kan aabọ ọganjọ oru, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn, wọn si n fipa jalẹkun lati mu awọn ti wọn fẹẹ ji gbe. Ọna ti wọn gba wa naa la gbọ pe wọn gba lọ.
Alaga ijọba ibilẹ Chikum to ṣẹṣẹ fipo silẹ, Mallam Samaila Leeman, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin, o leeyan mẹrinla lawọn ṣi fidi ẹ mulẹ pe wọn ji gbe, awọn o si mọ pato inu igbo ti wọn ko wọn lọ gan-an.
Oru ọjọ to ṣaaju eyi, ọjọ Iṣẹgun mọju Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn janduku agbebọn yii ti kọkọ ji awọn ọmọleewe ookan din laaadọjọ (149) nileewe Bethel Baptist School, to wa nijọba ibilẹ Chikum yii kan naa. Ori ko awọn mejidinlọgbọn lara awọn akẹkọọ naa yọ nigba ti wọn raaye sa mọ wọn lọwọ loju ọna bi wọn ti n lọ ninu igbo ninu okunkun oru naa, ṣugbọn awọn akẹkọọ mọkanlelọgọfa (121) lo ṣi ha sakata awọn ọdaju afẹmiṣofo ẹda yii titi di ba a ṣe n sọ yii.
Bi gbogbo eyi ṣe n ṣẹlẹ lọwọ nipinlẹ Kaduna, bẹẹ lawọn agbebọn kan tun sakọlu ilu Dabna ni kansu Hong, nipinlẹ Adamawa, nnkan bii aago meje aabọ owurọ Ọjọruu, Wẹsidee ni wọn ni wọn ṣadeede ya de, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ, eeyan mẹrinlelogun lo ba iṣẹlẹ ọhun rin, tawọn mẹjọ mi-in si fara gbọgbẹ gidi.
Ọgbẹni kan to porukọ ara ẹ ni Innocent Geoffery sọ fawọn oniroyin pe ibi toun n gbe ko jinna sibi tiṣẹlẹ yii ti waye, o fidi ẹ mulẹ pe awọn to ṣe akọlu naa ki i ṣe Boko Haram, o lawọn Fulani agbebọn ni, wọn ko si ji ẹnikẹni gbe lọ, niṣe ni wọn n yinbọn fun gbogbo eeyan ti wọn ba ti ri.
Alaga kansu Hong, Ọgbẹni James Pakuma fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o leeyan mọkandinlogun lawọn ṣi ri ka pe awọn apaayan naa yinbọn pa, ati pe gbogbo awọn to fara gbọgbẹ lawọn ti ko lọ sọsibitu nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Pakuma ni afaimọ ko ma jẹ pe niṣe lawọn agbebọn naa waa gbẹsan bawọn eeyan kan ṣe pa Fulani darandaran kan lagbegbe naa ni ọsẹ meloo kan sẹyin.
Oun naa fidi ẹ mulẹ pe awọn to ṣakọlu yii ki i ṣe Boko Haram rara, tori wọn n sọ ede Fulfide tawọn ẹya Fulani maa n sọ, awọn kan lara wọn si n sọ ede Hausa si ara wọn.
Iṣẹlẹ mi-in to fara pẹ eyi ni bawọn eeṣin-o-kọ’ku Boko Haram kan ṣe ya bo ilu Katarko tibọn-tibọn, nijọba ibilẹ Gujba, ipinlẹ Yobe.
Taara ni wọn lawọn apaayan yii fori le ọja to yẹ ko waye laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ti wọn si le awọn eeyan naa sa koloba koloba.
Wọn ni niṣe lawọn Boko Haram yii bẹrẹ si i ko ọja awọn to ti patẹ lẹyin ti kaluku wọn ti sa asala fẹmii rẹ, wọn ko ọpọ nnkan jijẹ ati owo, wọn si ba ẹsẹ wọn sọrọ lẹyin ti wọn ṣetan.
Ninu akọlu ọhun, a gbọ pe wọn ṣe iya ẹni ọgbọn ọdun kan leṣe, pẹlu aburo rẹ ti wọn jọ wa sọja ọhun.
A gbọ pe awọn kan lara awọn to ṣakọlu yii kọju ija sawọn ṣọja to n ṣeto aabo lagbegbe Damaturu, tawọn mejeeji si jọ gbẹna woju ara wọn.
Ba a ṣe gbọ, wọn loorekoore lawọn afẹmiṣofo n ṣakọlu si ọja yii, ti wọn si n ji awọn eeyan ni ounjẹ ko.