Monisọla Saka
Bii ere bii ere, oju ọna marosẹ Eko si Ibadan ti n di igbo ibẹru, o ti n di ibuba awọn agbenipa ati agbenigbowo. Boya lo le ti i ju ọsẹ meji lẹyin ti wọn gbe Ọjọgbọn Fasiti Ibadan atawọn akẹkọọ Poli Abẹokuta kan ti wọn tun fi ṣọṣẹ mi-in lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Lọjọ Tusidee ọhun lawọn agbebọn ti wọn wọ aṣọ awọn ologun kọ lu awọn mọto loju ọna marosẹ Eko si Ibadan
Awọn agbebọn ti wọn lo ṣee ṣe ki wọn jẹ ajinigbe yii ni wọn ṣadeede rọ jade lati inu igbo ti ko fi bẹẹ jinna si Ṣagamu Interchange, lọna to kọju s’Ekoo, wọn si bẹrẹ si i yinbọn sawọn onimọto ero mejidinlogun to n na awọn ipinlẹ kan sikeji ọhun.
Ọkan ninu awọn ti wọn ṣe kongẹ awọn ẹni ibi yii ti ko darukọ ara ẹ ni, “Ori lo ko wa yọ lọwọ awọn agbebọn yẹn, ṣugbọn ọpọlọpọ wa la fara pa latari ọta ibọn ti wọn yin fun wa, gbogbo ara mọto si ni wọn ti fibọn da bira si lara.
Bẹẹ lọkunrin kan naa tibọn ba n ṣalaye ninu fidio pe,” Mo tiẹ kọkọ lero pe mo ti ku ni, nitori ọta ibọn ba emi naa. Niṣe ni wọn doju kọ mọto wa ti wọn da ibọn bo wa, gbogbo wa la sare bẹrẹ mọlẹ sinu mọto nibẹ, ayafi awakọ wa nikan to jẹ pe oun gangan ni wọn foju sun. Wọn ro pe gbogbo wa ti ku ni, ni wọn ba pada sinu igbo”.
Ko pẹ pupọ lẹyin naa lawọn ikọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ati Ọyọ de si ibudo iṣẹlẹ naa lati doola awọn ero inu ọkọ ọhun.