Faith Adebọla
Afaimọ ko ma jẹ pe awọn jaduku agbebọn yii mọ-ọn-mọ doju le ipinlẹ Kaduna ni, pẹlu bi wọn ṣe n fojoojumọ ji awọn ọmọleewe ko kaakiri ipinlẹ naa lati bii ọsẹ kan sẹyin, awọn ọmọleewe pamari ni wọn tun lọọ rẹbuu lọna laaarọ ọjọ Aje, Mọnde yii, ti wọn si ji wọn gbe wọ’gbo lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, niṣe lawọn agbebọn naa lọọ lugọ de awọn ọmọọlewe UBE Primary School, to wa niluu Rama, nijọba ibilẹ Birnin Gwari, nipinlẹ Kaduna, wọn ni bawọn ọmọ naa ṣe n fẹsẹ rin lọ sileewe wọn lati wọle laaarọ ọjọ Aje ni wọn da wọn duro, niṣe ni wọn n he wọn lapa sori ọkada, ti wọn si n gbe wọn sa lọ.
Olugbe agbegbe ọhun kan, Abdulsalam Adam, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), pe ọkada mejila loun foju ara oun ri, tawọn agbebọn fi ko awọn ọmọọlọmọ lọ, o ni tiṣa ileewe ọhun mẹta lo wa lara awọn ti wọn ji gbe naa.
“Awọn tiṣa mẹta lo wa lara awọn ti wọn ji gbe naa, a o si ti i mọ iye awọn akẹkọọ ti wọn ko sa lọ, ṣugbọn awọn ẹṣọ alaabo ilu, awọn fijilante wa, atawọn ọdọ mi-in ti bẹrẹ si i wa awọn igbo agbegbe naa, wọn si ti n tọpasẹ awọn janduku yii.”
Wọn ni obi kan to porukọ ara ẹ ni Halilu sọ pe niṣeju oun ni wọn ti gbe ọmọ oun sori ọkada. O loun pariwo, ṣugbọn awọn agbebọn naa fẹẹ yinbọn, loun ba sa pada. Ẹlomi-in, Mohammadu Birnin Gwari, to n gbe ilu Birnin Gwari, sọ pe mọlẹbi oun ni meji lara awọn tiṣa tawọn agbebọn naa ji gbe. O lorukọ wọn ni Umar Hassan ati Rabiu Salisu Takau.
Kansẹlọ agbegbe ọhun, Aliyu Isa, sọ fawọn oniroyin pe oun o ti i le fidi ẹ mulẹ boya awọn ọmọleewe wa lara awọn ti wọn ji gbe ati iye wọn pato, ṣugbọn loootọ ni iṣẹlẹ naa waye. O lawọn agbebọn naa ti kọkọ ji awọn maaluu kan ko lagbegbe naa.
A gbọ pe awọn agbofinro ti de ibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti bẹrẹ iwadii, wọn nijọba maa sọrọ lori iṣẹlẹ yii laipẹ.
Tẹ o ba gbagbe, eyi ni iṣẹlẹ kẹrin laarin bii ọsẹ kan ti awọn agbebọn maa ji awọn ọmọleewe ko ni leralera ni ipinlẹ Kaduna. Eyi to ṣẹlẹ kẹyin waye loru Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, awọn akẹkọọ mẹtadinlaaadọrin ni wọn lo ṣi wa lakata awọn jaduku naa, nigba ti ori ko awọn bii ọọdunrun akẹkọọ yọ lọjọ Aiku, Sannde yii, nigba ti wọn fẹẹ ji wọn gbe.