Ni nnkan bii aago kan oru ni awọn janduku agbebọn kan tun ya wọ ileewe girama kan ti wọn n pe ni Bethel Secondary School, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ko ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ti ko sẹni to ti i le sọ iye wọn lọ.
A gbọ pe ṣe ni wọn ya wọ inu ọgba ileewe naa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera lati dẹruba awọn akẹkọọ naa. Lasiko tawọn ọmọleewe naa sa jade lati sa asala fun ẹmi wọn ni awọn janduku yii bẹrẹ si i ko wọn, ko si ti i sẹni to mọ iye ti wọn jẹ di ba a ṣe n sọ yii.