Awọn agbebọn yinbọn lu igbakeji ọga ọlọpaa patapata, wọn pa ẹṣọ alaabo ẹ

Faith Adebọla

Ẹka ti wọn ti bojuto ọrọ pajawiri nileewosan ijọba to wa niluu Bauch, ipinlẹ Bauch, ni igbakeji ọga agba patapata nileeṣẹ ọlọpaa, AIG Audu Madaki, wa bayii, tawọn dokita n sapa lati doola ẹmi ẹ, latari bawọn afẹmiṣofo kan ṣe dena de e pẹlu awọn ẹṣọ to n tẹle e, wọn yinbọn fun un, wọn si pa ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọ.

Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ yii, ni akọlu naa waye lagbegbe Barde Zangidi, nijọba ibilẹ Toro, nipinlẹ naa, lasiko ti ọga ọlọpaa yii fẹẹ jade niluu Bauchi pẹlu ikọ ẹṣọ alaabo rẹ, wọn fẹẹ rin irinajo kan.

Ba a ṣe gbọ, wọn ni niṣe lawọn afẹmiṣofo naa lugọ de wọn lọna, bi wọn si ṣe wakọ de itosi ni wọn ti ṣina ibọn bolẹ, oju-ẹsẹ si ni awakọ to gbe Madaki ti lọri ọkọ pada, ki wọn le bọ lọwọ ewu, ibi ti wọn ti n sapa lati ṣẹri pada ni ibọn ti ba ẹṣọ to n tẹle ọga ọlọpaa naa to jokoo siwaju ọkọ, lẹgbẹẹ dẹrẹba, ẹsẹkẹsẹ lo si ti gbẹmi mi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Bauchi, Thomas Goni, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti da awọn agbofinro rẹpẹtẹ sagbegbe ti akọlu naa ti waye lati tọpasẹ awọn apaayan to ṣiṣẹ laabi yii.

Leave a Reply