Faith Adebọla
Inu ibanujẹ nla lawọn eeyan abule Wasinmi, nipinlẹ Ọṣun, wa bayii, ọfọ gidi lo ṣẹ labule naa, latari bawọn agbebọn kan ṣe ya wọbẹ lowurọ ọjọ Aiku, Sannde yii, ti wọn si yinbọn paayan mẹfa ninu mọlẹbi kan naa.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, Wale Ọlọkọde, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe loootọ niṣẹlẹ aburu naa waye, ṣugbọn awọn agbofinro atawọn ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC lagbegbe ọhun ti n tọpasẹ awọn agbebọn naa lọ bayii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oru mọju, nigba tawọn eeyan n sun lọwọ lawọn agbebọn naa ya wọn abule to wa laarin ilu Ikire ati Irewọle ọhun, loju ọna Ifẹ si Ibadan, nipinlẹ Ọṣun.
Ko ti i sẹni to le sọ pato orukọ awọn mẹfẹẹfa ti wọn pade iku oro yii, ṣugbọn awọn agbofinro ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari nipinlẹ Ọṣun.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa iṣẹlẹ yii.