Wọn ti mu Barry Jhay, ọmọ Sikiru Ayinde Barrister, ni Ghana, ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an

Dada Ajikanje

Orilẹ ede Ghana lọhun-ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, nibi ti ọkan ninu awọn ọmọ Oloogbe Dokita Sikiru Ayinde Barrister n gbe, iyẹn Barry Jhay,  owo ni wọn sọ pe o da oun ati ọkunrin kan pọ ki ija too de laarin wọn, nigba ti tọhun si ku laipẹ yii, ni wọn ba sọ pe oun lo pa a.

Loootọ Barry Jhay ni wọn n pe e, ṣugbọn orukọ ti Dokita Sikiru Ayinde Barrister ati iya to bi i fun lati kekere sọ ọ ni Oluwakayọde Junior Balogun. Orin loun naa n kọ ni Ghana to n gbe, ọrọ lo si ṣe bii ọrọ laarin oun ati ọkunrin puromota kan, Kashy Godson, toun naa n gbe Ghana, nni ọkunrin yẹn ba ku lojiji, ki oloju si too ṣẹ ẹ, wọn ni Barrister, iyẹn Barry Jhay, lo pa a.

Ohun ti AKEDE AGBAYE gbọ ni pe o pẹ ti ajọṣepọ ti wa laarin Barry Jhay ati ọkunrin ọmọ Ghana to doloogbe yii. Wọn loun gan-an ni puromota to maa n ba a gbe orin jade ki aarin wọn too daru.

Lojiji ni wọn sọ pe ija de si wọn laarin, Barry Jhay paapaa ni wọn lo jẹ ki awọn eeyan mọ pẹlu bo ṣe gba ori ikanni abẹyẹfo ẹ lọ, nibi to ti ṣalaye ohun to da wahala saarin wọn.

Nibi tawọn eeyan ti mọ pe ija ti de laarin ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister pẹlu ọkunrin to n jẹ Kashy Godson ni Ghana niyẹn.

Ṣa o, lọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii, ni gudugbẹ nla ja, ọkunrin puromota yii ku, n lawọn eeyan ba n sọ pe iku ọkunrin naa ki i ṣe oju lasan, o lọwọ kan abosi ninu, paapaa bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe niṣe ni ọkunrin naa para ẹ danu.

Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye lawọn eeyan ti n naka iku ojiji to pa a yii si Barry Jhay. Wọn ni wahala to ṣẹlẹ laarin wọn, eyi to mu un lọ sori ikanni tuita rẹ, nibi to ti salaye ija wọn fun gbogbo aye ṣee ṣe ko ni i ṣe pẹlu iku to pa a.

Yatọ si ọrọ ija ti Barry Jhay ṣọ tawọn eeyan fi n sọ pe o mọ daadaa nipa iku ọkunrin yii, wọn ni aago ti ọkunrin naa n lo ni wọn tun ba lọwọ ẹ, eyi to mu awọn eeyan maa sọ pe wọn gbọdọ wadii ọmọ Barrister daadaa lori iku to pa ọkunrin naa.

Ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 1993, ni wọn bi Barry Jhay, Alhaji  Sikiru Ọlọlade Ayinde Balogun, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ayinde Barrister lo bi i, akọbi lobinrin fun gbajumọ olorin ti ti doloogbe nni, IK Dairo, lo si bi i fun ọkunrin olorin fuji naa.

Ọkan ninu awọn ọmọ Barrister to sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe awọn mọlẹbi ti gba lọọya ti yoo ṣoju ọmọ wọn lorilẹ-ede Ghana ti wọn ti mu un lori ẹsun pe oun lo pa puromota ẹ.

Obinrin to sọrọ yii fi kun un pe, “Barry Jhay jẹ ọmọ kan to ni iwa tutu, ọrẹ gidi loun ati ọkunrin ti wọn lo pa yii. Oun gan-an lo jẹ ko wa ni Ghana, loootọ la gbọ pe ija ṣẹlẹ laarin wọn, ṣugbọn ọrọ naa ko to ohun ti eeyan le maa lepa ẹmi ẹni keji kiri si debii pe yoo pa a. Laipẹ yii lo fun Barry Jhay ni aago olowo nla, ohun ti awa si mọ ni pe eto idajọ wọn ni Ghana dara pupọ wọn ko ni i fiya jẹ alaiṣẹ.

“Igbagbọ awa mọlẹbi ni pe Ọlọrun maa ko o yo, nitori nigba ti ọrọ yẹn kọkọ ṣẹlẹ, paapaa lọjọ ti ọkunrin yen ku gan-an, ariwo to gba ilu ni pe Barry Jhay lo pa a, nitori tiyẹn ti kọkọ lọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ, nibi to ti ṣalaye pe oun ati puromota oun ja pẹlu ẹjẹ lẹnu. Ṣugbọn a dupẹ pe nigba to maa fi di ọjọ meloo kan si i, ariwo ti wọn n pa kiri pe oun lo pa a ti rọlẹ. Ọmọ jẹẹjẹ ni, orin lo sọ pe oun fẹẹ kọ, to si n kọ ọ.”

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọmọkunrin naa wa latimọle lorileede Ghana, taọn mọlẹbi si n ṣapa lati yọ ọ.

Leave a Reply