Awọn agunbanirọ dawati nibi ikọlu tawọn agbebọn ṣe sawọn ajọ eleto idibo

Monisọla Saka

Eeyan mẹfa ni wọn ti dawati bayii nibi ikọlu tawọn agbebọn ṣe si ọkọ bọọsi Hummer mẹfa kan, lasiko tawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), ẹka ti ipinlẹ Kogi, n ko nnkan eelo idibo dari bọ loru mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Gẹgẹ bi Ileeṣẹ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣe sọ, oru mọjumọ ọjọ Aiku, ni nnkan bii aago meji oru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii, lawọn janduku ọhun deede ja lu wọn lagbegbe Ọbajana, ti ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa si fara gbọta ibọn, titi mọ awọn agbofinro atawọn awakọ naa.

Awọn agunbanirọ meji, ti wọn n sinru ilu lọwọ atawọn mẹrin ti wọn ti sin ilẹ baba wọn tan, ni wọn n wa bayii. Gbogbo awọn ti wọn fara pa ni wọn ti n gbatọju nileewosan ijọba apapọ, Federal Medical Centre, to ti di ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun ijọba, Federal University Teaching Hospital, Lọkọja, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa.

Ọkan ninu awọn awakọ ọhun, Salisu Ibrahim, ti wọn yinbọn fun lẹsẹ ọtun ẹ, to si ti n gbadun diẹdiẹ l’ọsibitu ọhun, sọ fun akọroyin NAN, pe ojiji lawọn ẹni ibi ọhun ja lu awọn.

“Lati Abuja la ti n dari pada lọ si Lọkọja pẹlu esi idibo awọn aṣofin ti wọn ṣe nibẹ, tawọn eeyan yii fi waa ṣekọlu si wa. Gbogbo awọn ọkọ bọọsi mẹfẹẹfa ti wọn to tẹle ara wọn ni wọn fọwọ ba, latibẹ ni ọpọlọpọ wa ti fara pa. Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹnikẹni ko ku ninu wa, amọ mo gbọ pe awọn agunbanirọ kan ti dawati lasiko ti wọn ya bo wa loru yẹn”.

Bakan naa ni wọn tun ni adari gbogbogboo fun ẹka ti wọn ti n ṣe akọsilẹ nileeṣẹ ologun ori ilẹ, Commander Headquarters Command Army Records, Major General Sunday Igbinomwanhia, ọga agba alakooso eto idibo nipinlẹ Kogi, Hale Longpet, ati adari ajọ to n ṣakoso awọn agunbanirọ, NYSC nipinlẹ naa, Mofoluwaṣọ Williams, ti lọọ ṣabẹwo sawọn eeyan ti wọn n gbatọju lọwọ nile iwosan ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi, SP Williams Ovye-Aya, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ.

 

Leave a Reply