Awọn ajinigbe ṣ’ọṣẹ l’Akoko, wọn pa dẹrẹba, wọn tun ko ero rẹ wọgbo lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọrọ awọn ajinigbe to n ṣoro bii agbọn nipinlẹ Ondo ti waa di egbinrin ọtẹ to jẹ pe bi wọn ti n pa ọkan ni omiran tun n ru pẹlu bi wọn tun ṣe ji ọpọlọpọ awọn ero ọkọ kan gbe lagbegbe Akoko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lẹyin ti wọn ti yinbọn pa awakọ bọọsi ọhun.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu agba ilu kan, Alaaji Ibrahim Kilani, ẹni to filu Afin Akoko ṣebugbe, pe iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ naa laarin Akùnnù si Ìyẹ̀rẹ́ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko.

Awọn agbebọn naa lo ni wọn yinbọn pa awakọ bọọsi ero GUC ọhun lasiko ti wọn n huwa ibi wọn ọhun, lẹyin naa ni wọn fipa ko gbogbo awọn ero yooku wọnu igbo lọ. Ọmọdebinrin kan lo ni awọn eeyan ba ninu ọkọ naa, nibi to ti n kigbe lẹyin ti wọn ti ji awọn obi rẹ gbe sa lọ.

Alaaji Kilani ni ko pẹ rara tawọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn ṣọja fi de si ojuko ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye. Gbogbo awọn ẹṣọ alaabo ọhun lo ni wọn ti wọnu igbo lati doola awọn eeyan naa lọwọ awọn to ji wọn gbe bo tilẹ jẹ pe akitiyan wọn ko ti i so eeso rere lasiko ti awa fi ń ko iroyin yìí jọ lọwọ.

Leave a Reply