Faith Adebọla
Inu ṣibaṣibo ni awọn alaṣẹ banki Sterling, atawọn agbofinro wa bayii nipinlẹ Bayelsa, latari bawọn janduku ẹda ti wọn fura pe ajinigbe-gbowo ni wọn ṣe lọọ ji ọkan lara awọn maneja banki naa, Abilekọ Nneka Enuka Ugonochie, ti wọn si wọ obinrin naa wọnu igbo tẹnikan o ti i mọbi ti wọn wa di ba a ṣe n sọ yii.
ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn ajinigbe naa wọṣọ bii ṣọja ni ikorita PDP, to wa ni titi marosẹ Sanni Abacha, eyi to gba aarin ilu Yenagoa, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Bayelsa kọja, laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa yii, ibẹ ni wọn ti huwa laabi wọn.
Ṣaaju lawọn kan to mọ nipa iṣẹlẹ yii ti sọ pe wọn ti ṣekilọ fun obinrin ọga agba banki yii lati paarọ ile to n gbe, pe ko lọọ maa gbe ibomi-in latari bi wọn ṣe sọ pe ile naa ko jinna si ibuba ti wọn ti mu awọn ogbologboo ajinigbe meji kan, John Ewa, tawọn eeyan mọ si John Lyon, ati ẹni keji rẹ, Emmanuel Agase, lọjọsi.
Ṣugbọn obinrin naa ko tẹle amọran yii, boya nitori awọn agbofinro meji tijọba pese fun un lati maa daabo bo o, ti wọn si n ṣọ ile rẹ.
Wọn tun ni nigba kan ti gbogbo nnkan gbowo lori, obinrin naa ko tun ni awọn ọlọpaa to n ṣọ ọ mọ, wọn lo lowo ti ipese aabo naa n na oun ti pọ ju, bi wọn ṣe wi, ati pe ọkan rẹ balẹ diẹ nigba tọwọ tẹ awọn ajinigbe kan nitosi ile rẹ, Emmanuel ati John.
Ohun tawọn kan n sọ ni pe afaimọ ko ma jẹ awọn ẹmẹwa John Lyon ti wọn sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ ni wọn wa nidii iṣẹlẹ ijinigbe ọga banki yii.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa, CP Romokere Ibani, to fọrọ iṣẹlẹ yii lede laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa ta a wa yii, sọ pe, awọn afurasi ajinigbe mẹrin ti wọn mura bii ṣọja ni wọn da Abilekọ Nneka duro lasiko to n lọ sibi iṣẹ rẹ laaarọ ọjọ Ẹti ọhun, ati pe oun funra rẹ lo wa mọto lọjọ naa.
Kọmiṣanna ni iwadii ti bẹrẹ, awọn si ti n tọpasẹ awọn ajinigbe naa lati doola ẹmi maneja yii.