Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ajinigbe ji ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Olominira Benin kan gbe l’Ọjọbọ to kọja yii, loju ọna Matale, Okuta Wẹwẹ, n’Imẹkọ, ipinlẹ Ogun. Ẹgbẹrun lọna igba,(200,000) ni wọn ni kawọn ẹbi ẹ mu wa ki wọn too da a silẹ, ṣugbọn awọn ẹbi ko rowo ọhun san, wọn si dunaa-dura titi, awọn ajinigbe pada ge ọwọ ọhun si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, taati taosan, iye ti ẹbi san ti wọn fi da eeyan wọn silẹ niyẹn.
Ohun ti a gbọ ni pe iṣẹ pẹẹpẹẹpẹ ni ọkunrin ara Benin naa wa lọ si Imẹkọ ti i ṣe aala ilu wọn ati Naijiria, afi bo ṣe bọ sọwọ awọn ajinigbe marun-un kan ti wọn ni Fulani ni wọn. Ni wọn ba gbe e wọgbo lọ.
Balogun Imẹkọ Isalẹ, Oloye Ganiu Akinlẹyẹ, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣalaye pe awọn to ji ọkunrin naa gbe tilẹ ti ṣa a ladaa lori, wọn ti da sẹria fun un bi wọn ṣe n beere ẹgbẹrun lọna igba lọwọ rẹ.
Ṣugbọn nigba ti wọn kan si awọn ẹbi ẹ ti wọn ro pe yoo kowo wa, niṣe lawọn ẹbi n fọwọ ra ara, wọn ko ni iru owo bẹẹ lọwọ lati fi gba eeyan wọn silẹ.
Nigba to di ọjọ Satide ti awọn ẹbi ko ti i rowo naa ko kalẹ, afi ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ti wọn tu jọ, awọn ajinigbe naa gba a bẹẹ bii igba teeyan n ta ọja fun onibaara, ni wọn ba yọnda ọmọ Benin naa, wọn ja a sẹgbẹẹ ọna lagbegbe Ayedire, labule Eebefun, n’Imẹkọ.
Ori rẹ ti wọn ṣa ladaa ṣi wa nibẹ ti ko ti i san, iyẹn lo ṣe jẹ ileewosan lo ṣi wa lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, to n gba itọju.