Ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo bẹrẹ si i fiya jẹ ẹnikeni to ba tun da abẹ fun ọmọbinrin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Kọmiṣanna fọrọ ofin ati eto idajọ, Ọjọgbọn Oyelọwọ Oyewọ ati ẹgbẹ ẹ lẹka eto ilera, Dokita Bashir Bello, ni wọn sọrọ yii nibi ipolongo ti ajọ Hacey ṣe fawọn adari awujọ atawọn oniroyin niluu Ọyọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii pẹlu atilẹyin igbimọ to n gbogun ti ifiya jẹ awọn obinrin ninu ajọ agbaye ta a mọ si United Nations.

Dokita Bello, ẹni ti Akọwe agba ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ yii, Dokita Ayọọla Adebisi, ṣoju fun, sọ pe “ofin kan ti wa bayii to sọ ọ deewọ fun ẹnikẹni lati maa fiya jẹ awọn obinrin.

“Ileeṣẹ to n ri si ọrọ igbaye-gbadun awọn obinrin lo ṣagbatẹru abadofin naa nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ. Ni kete ti wọn ba ti sọ ọ dofin tan la oo bẹrẹ si i maa lo o lati fiya jẹ awọn to ba n da abẹ fun ọmọbinrin tabi ti wọn n fiya jẹ obinrin.

Nigba ti o n ṣapejuwe abẹ dida fọmọbinrin gẹgẹ bii aṣa ti ko b’agba mu mọ laye ta a wa yii, Amofin Azeezat Wẹmimọ Owolabi, ẹni to sọrọ lorukọ kọmiṣanna feto idajọ, rọ gbogbo awọn to ṣi n ṣe bẹẹ lati jawọ nibẹ nitori pe ipalara ti kinni naa n ṣe fun iru awọn ọmọbinrin bẹẹ ko kere, bo si ṣe ṣe n pa wọn lara lo n ṣakoba fun ọjọ iwaju wọn pẹlu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ofin ọdun 2020 ti waa to sọ abẹ dida deewọ, ṣugbọn ki i ṣe ibi gbogbo lawọn agbofinro le maa wa ni gbogbo igba. Iyẹn lo fi jẹ pe gbogbo eeyan lo ni ipa lati ko pẹlu fifi ẹjọ ẹni to ba dabẹ fọmọ sun awọn agbofinro ki wọn le ṣeto lati fiya to tọ jẹ ẹ nilana ofin.

Ninu ọrọ tiẹ, oludari àjọ Hacey to ṣeto ipagọ ọlọjọ mẹta naa, Omidan Rhoda Robinson, sọ pe pataki ipagọ ọhun ni lati da awọn eeyan lẹkọọ lati maa gbogun ti aṣa abẹ dídá fawọn ọmọbinrin.

Lara awọn to kopa nibi eto ọhun ni oludari ajọ to n ri si eto itaniji nilẹ yii, National Orientation Agency, Abilekọ Fọlakẹ Ayọọla, ati aṣoju CP Ngozi Onadeko ti i ṣe ọga agba awọn olopa ipinlẹ Ọyọ pẹlu awọn eeyan pataki mi-in.

 

 

Leave a Reply