Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn afurasi ajinigbe kan ti ṣakọlu si ọkọ akero bọọsi kan ni opopona to lọ lati ilu Iye si Iṣan-Ekiti, nijọba ibilẹ Ilejemeje, nipinlẹ Ekiti.
Awakọ naa, Ọgbẹni Dare Ilelabowo, atawọn mẹrin mi-in la gbọ pe wọn ṣi wa lakata wọn lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ko si sẹni to mọ ibi ti awọn ajinigbe naa ko wọn lọ. Ọmọ ẹgbẹ Amọtẹkun kan ti ko fẹ ka darukọ oun to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii ṣalaye pe ọkọ akero naa n bọ lati ilu Iye-Ekiti, to gba ilu Iṣan-Ekiti kọja. A gbọ pe ilu Ado-Ekiti gan-an ni dẹrẹba yii n lọ pẹlu ero marun-un to wa ninu ọkọ naa ti awọn agbebọn fi yọ si i lojiji, ti wọn si ko gbogbo wọn wọnu igbo lọ.
Ọkan lara awọn ero ọkọ naa to mori bọ sọ pe ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, loun ti n bọ lọjọ iṣẹlẹ yii, oun si wọ ọkọ lati Iye-Ekiti, oun n lọ si Ado-Ekiti.
O ṣalaye pe bi awọn ṣe de aarin igbo kan ni awọn ajinigbe yii bẹ ja oju ọna, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ. Eyi lo ni o mu ki ọkọ toun wọ naa ko si koto nla kan to wa loju ọna naa, oju-ẹsẹ lo ni awọn agbebọn bii marun-un ti wọn dihamọra pẹlu oriṣiiriṣii ohun ija oloro, ti wọn si tun da nnkan boju, ka awọn mọbẹ.
Okunrin yii ni niṣe ni wọn paṣẹ fun dẹrẹba ọkọ naa pe ko bọ silẹ, ti wọn si paṣẹ fun awọn ero inu ọkọ pe ki wọn dojubolẹ.
O ni nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ko awọn loun ti dọgbọn sa mọ wọn lọwọ, toun si sa wọnu igbo kijikiji kan to wa loju ọna naa lọ.
O fi kun pe lẹyin iṣẹju diẹ loun jade soju ọna, toun si ri ọlọkada kan ti oun da duro to pada gbe oun de ilu Ọyẹ-Ekiti.
Oun lo lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti gẹgẹ bo ṣe sọ. Awọn ọlọpaa yii lo lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbe ọkọ bọọsi ti wọn ji ero inu rẹ ko lọ yii wa si agọ wọn.
Ni kutukutu aarọ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ajinigbe yii pe mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe yii pe ki wọn lọọ wa miliọnu lọna aadọjọ (150m) wa kawọn too le tu wọn silẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ọga agba ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Joe Kọmọlafẹ, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe ẹṣọ Amọtekun ti bẹrẹ iṣẹ lati gba awọn ti wọn ji gbe naa silẹ lai fara pa.
Ajagun-fẹyinti yii sọ pe awọn eeyan awọn pẹlu ileeṣẹ alaabo mi-in ti wa ninu igbo ti wọn n ṣe iṣẹ takuntakun lati ṣawari awọn eeyan naa.
Tẹ o ba gbagbe, oju ọna yii kan na ni wọn ti ji kọmiṣanna fun eto ọgbin nipinlẹ Ekiti gbe, ti wọn si yinbọn pa dẹrẹba rẹ to jẹ kansẹlọ nijọba ibilẹ Ilejemeje, nipinlẹ Ekiti, ninu oṣu kẹrin, ọdun to kọja.