Mọgaji di alaga ere idaraya ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq,  kede Ọgbẹni Bọla Mọgaji, gẹgẹ bii alaga tuntun lẹka ere idaraya nipinlẹ Kwara, to si ni iriri rẹ yoo mu idagbasoke ba ẹka naa.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti kede iyansipo rẹ ati awọn miiran.

Mọgaji kẹkọọ jade nile-ẹkọ giga Fasiti ilu Ibadan, o si ti ṣiṣẹ lawọn ileeṣẹ ere idaraya lẹka oriṣiiriṣii jake-jado orile-ede yii. Bakan naa lo ti figba kan jẹ ọkan lara igbimọ ere idaraya nipinlẹ Kwara laarin ọdun 1977 si 1995, gẹgẹ bii akọni mọ-ọn-gba.

Gomina tun yan Ọmọwe Ọlarinoye Steve Abiọdun lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, gẹgẹ bii adari agba lẹka ere idaraya nipinlẹ naa. Ọkunrin yii kẹkọọ jade nile-ẹkọ giga Fasiti Ahmadu Bello, nipinlẹ Kaduna.

 

Awọn miiran to tun yan sipo ni : Dele Abubakar; Abdullahi Lade; Lanre Elijah; Makanjuola Monisọla Yẹmisi; Roseline Raphael; Balikis Abọlọrẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply