Awọn ajinigbe ọna Eko s’Ibadan, Makinde ṣeun

O Ṣoju Mi Koro!

Nigba miiran, ẹjọ ati atotonu ki i mu nnkan ya, bi ọrọ ba ṣẹlẹ gbara, keeyan tete wa ojutuu si i ni.  Fun bii odidi ọsẹ meji ti ọrọ awọn ajinigbe ọna Ibadan fi ba ọna mi-in yọ, awọn ọlọpaa ijọba Naijiria ko ti i mọ ohun ti wọn yoo ṣe, tabi ka sọ pe araalu ko ri kinni kan ti wọn ṣe, paapaa awọn ti wọn wa nilẹ Yoruba nibi.

Eeyan ko si le ba wọn wi si eyi o, nitori ki wọn too le ṣe ohunkohun, aṣẹ gbọdọ wa lati Abuja, bi aṣẹ ko ba wa, bi ẹni kan ba gbe ọwọ kankan ninu wọn, ibi ti yoo ba ara rẹ ko ni i dara. Ohun ti awọn eeyan si ṣe n pariwo lati ọjọ yii wa ree pe ki ipinlẹ kọọkan ni ọlọpaa tiwọn, ki wọn le mojuto eto aabo adugbo wọn, ki wọn le kapa idaabobo awọn eeyan wọn.

Iru ohun ti wọn sọ lo ṣẹlẹ yii. Nigba ti awọn ọlọpaa ijọba apapọ ko i ti i mọ ohun ti wọn yoo ṣe lori ọrọ awọn ajinigbe, Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ sare ko awọn Amọtẹkun ti oun ni jade, wọn si to wọn lati abule Ogunmakin, nibi ti aala awọn ati ipinlẹ Ogun wa, titi de Abule Onigaari, ati titi de Too-geeti, nikọja Guru Maraji.

Loootọ ibọn ṣakabula lasan lawọn ẹṣọ yii ri gbe dani, ṣugbọn ibẹru pe ẹṣọ alaabo ni wọn yoo wa lara wọn. Bi awọn ajinigbe wọnyi ba fẹẹ dánà nibi kan tẹlẹ, bi wọn ba ri awọn Amọtẹkun yii, wọn yoo ro o daadaa ki wọn too ṣiṣẹ buruku ti wọn fẹẹ ṣe.

Inu eeyan ko le dun pe ibọn ṣakabula lasan lo wa lọwọ wọn, nitori ẹbẹ ni awọn ijọba ilẹ Yoruba ti n bẹ Buhari ati awọn eeyan rẹ pe ki wọn jẹ ki Amọtẹkun ni ibọn gidi lọwọ wọn, ṣugbọn ti wọn ko gba, ohun to n ba wọn lẹru ko ye ẹni kan. Ṣugbọn ẹmi awọn eeyan wa ni wọn fi n wewu, aabo awọn eeyan wa ni wọn n daru, ijọba ilẹ Yoruba ko si gbọdọ duro titi ti wọn yoo fi sọ adugbo yii di ilẹ Hausa lọhun-un, nibi ti awọn Fulani afẹmiṣofo ti gba awọn abule wọn lọwọ wọn, ti wọn si n ṣejọba tiwọn nibẹ, bi Gomina El-Rufai ti wi.

Ṣugbọn iṣoro to wa nibẹ naa ni pe awọn gomina tiwa ko ṣiṣẹ papọ, bẹẹ bi ọrọ ba ri bo ti ri yii, ko si ohun ti wọn le fi gba gbogbo ọmọ Yoruba ju ki awọn ijọba yii ṣiṣẹ papọ lọ. Nigba to jẹ ede kan naa la jọ n sọ, ẹya kan naa si ni wa, bi ijọba Ogun ba pawọ-pọ pẹlu ijọba Eko, ti ti Ọsun pawọ-pọ mọ ti Ọyọ, ti Ekiti ati Ondo si fọwọ kun wọn, yoo ṣoro ki awọn afẹmiṣofo tabi awọn ajinigbe too gba ilẹ wa lọwo wa, tabi ki wọn sọ awọn eeyan wa di suya, ki wọn maa rẹ wọn bo ti wu wọn, tabi ki wọn sọ wa di maṣinni ATM, ki wọn maa fi wa gbowo.

Ṣugbọn awọn eeyan wa ko ṣe bẹẹ. Bi ariwo ti n lọ to yii, ti wọn n jiiyan rẹpẹtẹ ko l’Ogun, ti wọn n ji wọn ko l’Ọyọọ, ijọba ipinlẹ Eko ko ṣe bii ẹni pe awọn gbọ, boya wọn ti ro pe kinni naa ko le kan awọn ni. Bo tilẹ jẹ pe Gomina Babajide Sanwoolu waa ba wọn ṣe mitinni nigba ti wọn fẹẹ da Amọtẹkun silẹ, nibi ti kinni naa mọ niyẹn. O han gbangba pe nigba to dele ni ọga rẹ to ti mọ pe oun fẹẹ dupo aarẹ pe e pe ko gbọdọ ba wọn lọwọ si iru ẹ, ko si Amọtẹkun kan ti Eko yoo ni. Bo si ti ṣe ri lati ọjọ naa wa niyẹn.

Awọn janduku wa, wọn ji ara Ọyọ gbe, ara Eko ni ko kan oun; wọn tun wa, wọn ko ogun ja wọn ni Ogun, ara Eko ni ko kan oun, ọrọ to kan awọn Ọyọ, to kan wọn l’Ogun, to kan wọn l’Ondo, igba wo ni ko ni i kan wọn l’Ekoo, ṣe o digba to ba ṣẹlẹ ka too gbẹnu soke maa pariwo ni, tabi oṣelu wo la n ṣe to pa laakaye wa bayii!

Iyẹn leeyan ṣe gbọdọ ki Makinde pe o ṣeun. Ibi ti Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti n ṣepade oriṣiiriṣii pẹlu awọn agbofinro, ti Eko fi han gbogbo aye pe awọn ko si lara Yoruba ti Fulani ajinigbe n jẹ niya, Makinde jade pẹlu iwọnba agbara ti ijọba rẹ ni, wọn si di aala adugbo tiwọn mu.

Eyi ni pe bi eeyan ba n lọ s’Ibadan lati Eko bayii, to ba ti kuro ni ibi aala awọn ara Ogun, ko fọkan balẹ, ko maa lọ sibi to n lọ ni. Ko si ohun to buru bi Abiọdun naa ba ko awọn Amọtẹkun rẹ soju ọna lati Ogunmakin titi de Ṣagamu, nigba ti awọn ọlọpaa ba ṣepade wọn tan, wọn yoo ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe.

Awọn Fulani ajinigbe ti ka wa mọ ilẹ Yoruba o, asiko yii kọ leeyan n fi eto aabo ṣe oṣelu, ki gbogbo gomina pata dide sọrọ yii ni. Fulani kan ko ko iran baba wa lẹru ri, ẹ ma jẹ ko ṣẹlẹ lasiko yii o!

Leave a Reply