Faith Adebọla
Alaga ẹgbẹ awọn darandaran onimaaluu, Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria (MACBAN), Alaaji Abubakar Abdullahi, ti inagijẹ rẹ n jẹ Danbardi, tawọn janduku agbebọn ji gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti dagbere faye lẹyin ọjọ keji lakata awọn ti wọn ji i gbe.
Atẹjade latọwọ Ọgbẹni Othman Ngelzarma, Akọwe apapọ ẹgbẹ MACBAN, ṣalaye lọjọ Abamẹta, Satide, yii pe iku Abubakar yii lo sọ ọ di ẹni karun-un tawọn janduku agbebọn, awọn ajinigbe atawọn to n jale maaluu yoo pa nipa ika lẹnu ọjọ mẹta yii lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn, bẹẹ awọn mọ pe ọpọ ọmọ ẹgbẹ naa lawọn ika ẹda yii n pa ti ko si akọsilẹ fun wọn.
“Alaaji Abubakar, ẹni ọdun mejidinlọgọta, to jẹ alaga ẹgbẹ MACBAN nijọba ibilẹ Lere, nipinlẹ Kaduna, lawọn ajinigbe ji gbe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, lẹyin tawọn mọlẹbi ẹ si ti san owo ti wọn beere fun itusilẹ rẹ lo jẹ oku rẹ ni wọn ba lẹgbẹẹ titi laṣaalẹ ọjọ keji, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsan-an, lọna to wọ ilu Lere.
‘‘A daro gidigidi pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe yii, a si fi ẹdun ọkan wa han pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ ati alakooso ẹgbẹ MACBAN, a ṣadura ki Allah rọ wọn lọkan lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii.
A n fi asiko yii ke si awọn agbofinro lati wadii iku ojiji yii ki wọn si fiya to tọ jẹ awọn ti wọn lọwọ ninu iwa odoro naa.
A fẹẹ ṣekilọ pe ti iwa ọdaran bii eyi ba n ba a lọ, o maa mu ko tubọ ṣoro fawọn darandaran lati ṣe ọrọ-aje wọn lorileede yii, eyi si maa mu ki ẹran wọn gogo gan-an.
A fẹ kijọba apapọ ṣeto ofin to maa daabo bo awọn darandaran kaakiri orileede yii, ki wọn le maa ṣọrọ-aje wọn lai si ifoya.