Awọn ajinigbe paayan kan l’Ekiti, wọn tun gbe ọga ṣọja lọ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe tun ti ṣọṣẹ nipinlẹ Ekiti bayii pẹlu bi wọn ṣe ji ajagun-fẹyinti kan, Jide Ijadare, pẹlu oṣiṣẹ ẹ kan gbe, bẹẹ ni wọn ṣeku pa eeyan mi-in lọsan-an oni.

Ẹnikan to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe ileeṣẹ epo pupa ti Ijadare to ṣiṣẹ fẹyinti nileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika da silẹ, eyi to wa loju ọna Ijan-Ekiti si Isẹ-Ekiti, lawọn eeyan naa ya bo, nigba ti wọn si yinbọn pa oṣiṣẹ ni wọn gbe ọkunrin naa ati oṣiṣẹ mi-in lọ.

A gbọ pe bi awọn ajinigbe naa ṣe de ni wọn da ibọn bolẹ, eyi to ko jinnijinni bo awọn to wa nibẹ, nigba ti wọn si ṣe nnkan ti wọn fẹẹ ṣe tan ni wọn gbe awọn eeyan naa lọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ kan, wọn si mori le ọna Isẹ-Ekiti

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe ni nnkan bii aago meji ọsan oni lawọn ajinigbe naa ṣọṣẹ, loootọ si ni pe wọn pa ẹni kan, ti wọn si ji awọn meji.

O ni Kọmiṣanna ọlọpaa, Tunde Mobayọ, ti da awọn agofinro si gbogbo agbegbe naa lati wa awọn eeyan ọhun ri ni gbogbo ọna, ati pe awọn ọlọdẹ ibilẹ n ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati ṣaṣeyọri lori ọrọ naa.

Leave a Reply