Awọn ajinigbe ti tu awọn arinrin-ajo ti wọn gbe l’Ẹrin-Ijeṣa silẹ

Florence Babaṣọla

Awọn arinrin-ajo meji tawọn ajinigbe ji gbe nitosi ilu Ẹrin-Ijeṣa, loju ọna Ileṣa si Akurẹ, lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja, la gbọ pe wọn ti tu silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu kan naira.

ALAROYE gbọ pe bo tilẹ jẹ pe ọwọ ko ti i ba eyikeyii lara awọn ajinigbe naa, sibẹ, awọn afurasi meje lọwọ awọn ikọ OPC ati JTF pẹlu awọn figilante tẹ ninu igbo naa.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn alaabo ti wọn ṣiṣẹ naa ninu igbo to wa laarin ilu Ẹrin-Ijẹsa ati ilu Ọmọ ti awọn ajinigbe ko awọn eeyan naa lọ ṣe sọ, miliọnu mẹwaa naira ni wọn kọkọ beere lori awọn mejeeji, ko too di pe wọn din in ku si miliọnu kan naira.

O ni ṣe lawọn ajinigbe naa n ko wọn si oriṣiiriṣii ibudo ninu igbo naa pẹlu bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe n finna mọ wọn. Lasiko ti iṣẹ naa si gbona lọwọ tẹ awọn afurasi meje ninu igbo naa, ninu eyi ti ọkan ninu wọn jẹ ọmọ abule kan nitosi ibẹ.

Ọkunrin yii ṣalaye pe ọwọ tun tẹ ọmọkunrin kan to n gun ọkada ninu igbo kijikiji naa, o ni ṣe lo gbe Fulani kan sẹyin, ti iyẹn si daṣọ boju. Awọn mejeeje naa lo sọ pe awọn ti fa le awọn ọlọpaa lọwọ.

Bo tilẹ jẹ pe alakooso awọn OPC nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Deji Aladeṣawẹ ko sọrọ nipa owo ti wọn fun awọn ajinigbe naa, ṣibẹ, o fidi rẹ mulẹ pe awọn afurasi meje lọwọ tẹ ninu igbo naa.

Leave a Reply