Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Tẹgbọn–taburo kan tawọn agbebọn ji gbe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, la gbọ pe wọn ti jajabọ lọwọ awọn janduku ọhun lẹyin bii ọsẹ kan ti wọn ti wa lakolo wọn.
Nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lawọn agbebọn ọhun da iya awọn ọmọ tọjọ ori wọn ko ti i ju bii ọmọ ọdun meji si mẹrin ọhun lọna lasiko to fẹẹ ṣi geeti ile ti wọn n gbe laduugbo Leo, lẹyin to siwọ iṣẹ oojọ rẹ lọjọ naa.
Bi iya wọn ṣe bọ silẹ lati ṣi geeti lawọn oniṣẹẹbi ọhun sare wọnu ọkọ rẹ, ti wọn si gbe awọn ọmọ mejeeji to fi sinu ọkọ sa lọ.
Ọjọ kẹta iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe awọn ajinigbe naa pe iya wọn lori aago, ti wọn ni ko san miliọnu mẹwaa Naira kiakia to ba ṣi fẹẹ foju ri awọn ọmọ rẹ laaye.
Nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn alaaanu kan ṣalabaapade awọn ọmọ mejeeji nibi ti wọn ko wọn ju si lagbegbe Okuta Ẹlẹrinla.
Awọn eeyan ọhun ni wọn sare ko awọn ọmọ iya meji naa lọ si tesan, nibi ti wọn ti kọkọ fọrọ wa wọn lẹnu wo ki wọn too ransẹ pe awọn obi wọn.
Ohun ta a gbọ ni pe ko din ni miliọnu marun-un Naira ti wọn gba lọwọ iya wọn ki wọn too yọnda wọn.