Ifa o fọre fun Secondus o, ile-ẹjọ lawọn o le da apero PDP duro

Faith Adebọla

Idajọ, ‘ki lo ti n wo latọjọ yii’ nile ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan to fidi kalẹ siluu Port Harcourt da fun Ọmọọba Uche Secondus, lori ẹjọ to pe lati da ẹgbẹ oṣelu to n jẹ Alaga fun, lọwọ kọ pe wọn o gbọdọ tẹsiwaju lori ipade apero ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ Abamẹta,Satide yii mọ, ile-ẹjọ ni aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ o, reluwee to ti lọ lọkunrin naa n ṣẹ’wọ si.

Igbimọ onidaajọ ẹlẹni mẹta kan lo panu-pọ gbe ipinnu wọn kalẹ lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee yii, niṣe ni wọn da Secondus lẹbi, wọn ni ibo lo ti wa latọjọ yii to ṣẹṣẹ waa n pẹjọ ta ko apero naa, wọn ni ipẹjọ rẹ yii ti pẹ ju, awọn si ri i bi i fifakoko ile-ẹjọ ṣofo lasan ni, eyi ti yoo tun san owo itanran fun.

Awọn adajọ naa ni asiko ti awọn alakooso wọọdu rẹ nipinlẹ Rivers ti lawọn da a lọwọ kọ, awọn si yọ ọ danu lọmọ ẹgbẹ PDP ni wọọdu awọn lo ti yẹ ko gba ile-ẹjọ lọ, ki i ṣe igba ti ẹgbẹ apapọ fẹẹ ṣe apero wọn rara.

Wọn ni nigba to laju silẹ ti wọn fi yọ ọ lẹgbẹ ni wọọdu, ti wọn tun yọ ọ lẹgbẹ nijọba ibilẹ rẹ, ti ko ja raburabu nigba naa, ko le maa waa ja poun loun gbọdọ dari apero ẹgbẹ PDP to fẹẹ waye yii, awọn o si le da ẹgbẹ PDP lọwọ kọ lori apero wọn, wọn ni ki ẹgbẹ naa maa ba eto wọn lọ ni tiwọn, ki Secondus pada si wọọdu ẹ lọọ yanju iṣoro to ni.

Tẹ o ba gbagbe,ọsẹ to kọja ni Ọmọọba Secondus gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ, to ni ki wọn ba oun paṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP pe wọn o gbọdọ ṣe apero ti wọn fẹẹ ṣe lọgbọnjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii mọ, nibi ti wọn ti maa yan alaga, igbakeji alaga, atawọn ijoye apapọ ẹgbẹ naa, ti yoo maa tukọ ẹgbẹ niṣo. Secondus ni oun ṣi ni alaga ẹgbẹ, oun loun si lẹtọọ lati dari apero naa.

Ṣugbọn awọn gomina ẹgbẹ PDP kan ti fọwọ sọya saaju pe ere itiju lọkunrin naa yoo gba bọ ile-ẹjọ nidii ẹjọ to pe yii, wọn lawọn o ni i dawọ ipalẹmọ apero duro ni tawọn.

Pẹlu ibi ti ẹjọ naa wo si bayii, orin ‘ba a ṣe fẹ ko ri, bẹẹ naa lo ri, emi la o ni i yọ si’ lọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati awọn agbaagba ẹgbẹ yoo bẹrẹ si i kọ lasiko yii, ireti si wa pe apero naa yoo waye bi wọn ṣe gbero rẹ.

Leave a Reply