Awọn ajinigbe to ji Emir ni Kaduna n beere igba miliọnu naira

Faith Adebọla

Miliọnu lọna igba naira (#200m) lawọn ajinigbe ti wọn ji Emir ilu Kajuru, Alaaji Alhassan Adamu, ati awọn mẹtala mi-in lara awọn mọlẹbi ẹ sọ pe awọn maa gba ki wọn too le da ọba alaye naa silẹ nigbekun wọn.

Ọkan lara awọn mọlẹbi to wa laafin rẹ niluu Kajuru sọ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde yii, pe awọn ajinigbe naa ti kan sawọn lori foonu.

O ni wọn tun ba ọkan lara awọn ijoye ilu Kajuru sọrọ, iye kan naa ni wọn sọ fun wọn pe ki wọn wa wa lati gba Ẹmia Adamu ati awọn mọlẹbi rẹ silẹ.

O lawọn oloye ti n fori kori lori ọrọ yii, awọn si ti sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna.

Leave a Reply