Faith Adebọla
Meji mi-in lara awọn akẹkọọ fasiti mẹtalelogun to wa lahaamọ awọn janduku ajinigbe nipinlẹ Kaduna lo tun ti doloogbe, awọn agbebọn lo yinbọn pa wọn lọjọ Aje, Mọnde yii.
Kọmiṣanna feto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, lo sọrọ yii di mimọ, o sọ pe: “O ba ni lọkan jẹ pe awọn agbofinro ti fidi ẹ mulẹ fun ijọba ipinlẹ Kaduna pe awọn ti tun ri oku awọn ọmọ Yunifasiti Greenfield, tawọn janduku agbebọn pa.
“A ti ko oku awọn oloogbe naa lọ si mọṣuari, a si ti fi iṣẹlẹ buruku yii to awọn alaṣẹ fasiti naa leti.
“Ijọba ipinlẹ Kaduna, eyi ti Mallam Nasir El-Rufai jẹ gomina rẹ kẹdun gidigidi lori iṣẹlẹ yii, o si ba obi awọn tọrọ yii kan kẹdun pẹlu.
“A fẹẹ fi da yin loju pe ijọba yoo gbe gbogbo igbesẹ to ba yẹ, to si bofin mu lori ọrọ yii.”
Iṣẹlẹ yii lo sọ iye awọn eeyan tawọn agbebọn naa ti da ẹmi wọn legbodo di mẹfa bayii.
Ọjọ Iṣẹgun to kọja, ogunjọ, oṣu kẹrin yii, lawọn agbebọn ya bo fasiti aladaani Greenfield, to wa niluu Kaduna, wọn yinbọn pa oṣiṣẹ ileewe kan, wọn si ji awọn akẹkọọ mẹtalelogun lọ, wọn ko wọn wọgbo tẹnikan o ti i mọ di ba a ṣe n sọ yii.
Lẹyin naa ni wọn ri oku awọn akẹkọọ mẹta lara awọn ti wọn ji ko ọhun, awọn agbẹbọn lo yinbọn pa wọn, ti wọn si lọọ gbe oku wọn ju si abule Kawanan Bature, ni Kaduna.
Aarẹ Muhammadu Buhari ti bawọn obi ọmọleewe yii kẹdun ninu atẹjade kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, o si kede iṣẹlẹ naa bii eyi to buru jọjọ, ti ko ṣee gbọ seti.
Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti sọ pe ijọba oun ko ni i fun awọn janduku agbebọn naa lowo, bẹẹ lawọn o ni i dunaa-dura pẹlu wọn.
A gbọ pe ẹgbẹrin miliọnu naira lawọn agbebọn naa lawọn maa gba kawọn too le da awọn ọmọleewe yii silẹ, aijẹ bẹẹ, awọn maa fẹmi awọn ọmọ naa ṣofo danu ni. ALAROYE gbọ pe awọn alaṣẹ ileewe naa tawọn obi ti tu miliọnu mẹẹẹdogun jọ, ṣugbọn aọn ajinigbe naa ni aọn ko ni i gba owo naa. Miliọnu lọna ẹgbẹrin lawọn yoo gba, aijẹ bẹẹ, ọkọọkan laọn yoo maa pa awọn ekẹkọọ to wa lakata awọn yii