Awọn ajinigbe wọle lọọ ji ọba alaye gbe laafin rẹ l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe to n ṣọṣẹ nipinlẹ Ekiti lọwọlọwọ ti gba ọna mi-in yọ bayii pẹlu bi wọn ṣe kọ lu aafin Ọbadu tilu Ilẹmẹṣọ-Ekiti, Ọba David Oyewumi, ti wọn si ji kabiyesi naa gbe.

Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ Ọjọru, Tọsidee, niṣẹlẹ naa waye niluu naa to wa nijọba ibilẹ Ọyẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, niṣe lawọn agbebọn naa fo fẹnsi aafin wọle lẹyin tawọn oloye ti wọn waa ṣepade ti lọ sile, bẹẹ ni wọn da ibọn bolẹ lati ko awọn ti wọn ba nibẹ ni papamọra. Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i beere ọba alaye naa, ti wọn si n fiya jẹ awọn ti wọn ri, eyi to tumọ si pe oun gan-an ni wọn n wa.

Bi wọn ṣe ri kabiyesi la gbọ pe wọn gbe e, wọn si wọ ọ kuro laafin lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ di akoko yii.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe nnkan to ba ni lọkan jẹ gbaa ni, ati pe ibọn tawọn eeyan ọhun fi waa ṣọṣẹ lagbara pupọ.

O waa ni iwadii ti bẹrẹ, ileeṣẹ ọlọpaa yoo si wa gbogbo ọna lati gba Ọba Oyewumi silẹ lọwọ awọn ajinigbe, ati lati mu awọn ọdaran naa.

Tẹ o ba gbagbe, ko ti i pe ọsẹ kan tawọn agbebọn kọ lu Elewu tilu Ewu-Ekiti, Ọba Adetutu Ajayi, lasiko to n lọ si Ayetoro-Ekiti lati ilu ẹ, ṣe ni wọn si yinbọn fun un lọwọ, ẹsẹ ati ikun lasiko to n gbiyanju lati sa fun wọn, eyi to sọ ọ dero ileewosan.

 

Leave a Reply