Awọn akẹkọọ fasiti yii lu ẹlẹgbẹ wọn pa nitori foonu l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn na akẹkọọ ẹgbẹ wọn lalupa, awọn alaṣẹ ileewe giga aladaani kan nipinlẹ Ọyọ, Ajayi Crowther University, ti le bii meloo kan danu ninu awọn akẹkọọ fasiti naa.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni wọn kede igbesẹ ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ pàtó iye akẹkọọ ti wọn le lọ gan-an faye gbọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lalẹ ọjọ Ẹti,  Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn ni akekọọ ti wọn lu pa yii ji ẹrọ ibanisọrọ ọkan ninu awọn ẹgbẹ ẹ ninu ọgba ileewe naa. Nigba ti Ọlọrun yoo si ba ẹni to ni foonu ṣe e, aṣiri amookunṣika tu, n loun atawọn ẹgbẹ ẹ ba pinnu lati kọ ọmọkunrin to jale naa lọgbọn.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe laarin awọn akẹkọọ to fi inu ọgba fasiti naa ṣebugbe niṣẹlẹ ọhun ti waye, ati paapaa nitori ọwọ alẹ lo bọ si, aaye gba awọn akẹkọọ wọnyi bọ sódì lati fiya jẹ ọmọkunrin ole naa kọja aala, nnkan bii wakati mẹjọ gbako ni wọn fi da sẹria fun un.

Lati bii aago mẹwaa ti wọn ti mu un ni wọn ti n lu u bii igba ti wọn n lu aṣọ ofi, aago mẹfa idaji si lu daadaa ki wọn too fi i lọrun silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn pada gbe ọmọkunrin naa lọ sileewosan fun itọju lati gbẹmi ẹ la, ko pẹ rara lọsibitu ti irora iya buruku to jẹ ẹ fi mu ẹmi ẹ lọ salakeji.

Ko pẹ rara ti okiki iṣẹlẹ yii fi kan, ṣugbọn abala to rin jinna ju ninu iroyin ọhun ni pe akẹkọọ kan ku nileewe ACU, gẹgẹ bii àgékúrú orukọ ileewe naa. Nigba tiroyin ọhun yoo si di ọrọ okeere tan, to jẹ pe bi ko ba lekan, o di dandan ko din, wọn ni nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun doju ija kọra wọn ni wọn lu ara wọn pa.

Nigba ti wọn n sọrọ lori iṣẹlẹ yii ninu atẹjade ti wọn fi sita nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, awọn alaṣẹ ileewe ọhun fidi ẹ mulẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iya àtọwọ́dá ti wọn fi sọ ọkunrin alaaye naa doloogbe pata lawọn ti da pada sile koowa wọn.

Ṣugbọn wọn ta ko abala to ni i ṣe pẹlu ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ninu iroyin naa ninu atẹjade wọn, wọn ni, “Lòdì si iroyin to n ja rainrain kiri nipa ọrọ o-ṣẹgbẹ-okunkun, ko ṣẹgbẹ-okunkun, a layọ lati fidi ẹ mulẹ, a ṣi n fi gbogbo ẹnu sọ ọ pẹlu idaniloju pe ko ṣọmọ ẹgbẹ okunkun laarin awọn akẹkọọ wa, nitori ileewe yii ko faaye silẹ fun ẹgbẹ okunkun ati ohunkohun to lodi sofin tabi to lewu fun awujọ wa.

“Ohun to ṣẹlẹ gan-an ree, akẹkọọ kan lo ji foonu, ti ọwọ si tẹ ẹ, ṣugbọn dipo ki wọn fa a le awa alaṣẹ lọwọ, niṣe ni wọn bẹrẹ si i fibinu lu u pẹlu bi ọrọ naa ṣe ka wọn kara to.

Iya ti wọn fi jẹ ẹni to ji foonu yii lo pada ṣokunfa iku ẹ. Gbogbo awọn to si lọwọ ninu ọrọ yii pata la ti le lọ.

“Ṣugbọn o ṣe pataki lati tun fidi ẹ mulẹ pe gbogbo awọn ta a le lọ wọnyi, ko si ọmọ ẹgbẹ okunkun kankan ninu wọn, nitori ko saaye iru ẹ fawọn akẹkọọ tiwa nibi”.

 

 

Leave a Reply