Awọn alatilẹyin Tinubu lọ si ọfiisi INEC, wọn ni eto idibo ti wọn ṣe daa gan-an ni

Ọrẹoluwa Adedeji

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn to jẹ alatilẹyin aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ya lọ si olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa to wa ni Zambezi Cresent, Maitama, niluu Abuja, nibi ti wọn ti lọọ fi atilẹyin wọn han si ajọ naa pe wọn ṣeto idibo to dara ju, ti ko ni eru tabi magomago kankan, to si mọyan lori ju lọ.

Akọwe ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun iyansipo Tinubu ati Shettima ti wọn pe ni Tinubu-Shettima Support Group, Tosin Adeyanju, lo ṣiwaju awọn eeyan naa lọ si ọfiisi ajọ eleto idibo ọhun.

Wọn ni ohun to gbe awọn wa sibẹ ni lati daabo bo aṣẹ ati agbara ijọba ti awọn ọmọ Naijiria finu findọ gbe le Aṣiwaju lọwọ, eyi ti awọn ko fẹ ki ohunkohun ṣe.

Adeyanju ni ko si ariyanjiyan kankan ninu ibo to gbe Tinubu wọle, nitori tidunnu tidunnu lawọn eeyan fi dibo fun un, ati pe iṣejọba rẹ ko ni i si fun ẹya tabi awọn eeyan kan, gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo wa fun.

Ṣugbọn ko pe ti wọn fibẹ silẹ ti awọn ẹgbẹ mi-in ti wọn n jẹ Coalition of the Civil Society Organisation (CSO) naa tun fi ẹhonu han lọ si olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo yii kan naa. Ẹsun pe wọn gbọjẹgẹ lasiko idibo ni awọn ẹgbẹ bii mejidinlogun to papọ di ẹyọ kan yii fi kan wọn.

Gẹgẹ bi ẹni to n ṣe kokaari ẹgbẹ naa, Dada Ọlayinka ṣe sọ, o ni INEC ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ pẹlu bi wọn ṣe kọ lati ṣeto idibo to ni akoyawọ ti wọn ti ṣeleri fun gbogbo ọmọ orileede yii ṣaaju eto idibo.

Dada ni ko too di ọjọ idibo yii ni ajọ yii ti sọ pe awọn ti fun awọn oṣiṣẹ awọn ni idanilẹkọọ to yẹ, bẹẹ lawọn fun wọn ni gbogbo ohun ti wọn nilo lati pese wọn silẹ fun eto idibo ọhun. Bẹẹ ni wọn ṣeleri pe bi wọn ba ti n dibo tan ni wọn yoo maa fi esi idibo naa ṣọwọ si ori ikanni awọn kaakiri ibudo idibo lorileede yii atawọn ileri mi-in.

O fi kun un pe gbogbo awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko ibo ati lẹyin ti ibo naa waye ko fi ajọ yii han bii ẹni to ṣe aṣeyọri kankan nitori ọpọ ni ko le dibo, awọn ibomi-in wa ti wọn ko ri awọn iwe eto idibo loju ọjọ, atawọn aleebu bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni aWọn darapọ mọ awọn ajọ agbaye mi-in ti wọn ti bu ẹnu atẹ lu eto idibo to ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to buru ju ninu itan ilẹ Naijiria naa, nitori bo ṣe kun fun magomago ati ojoro rẹpẹtẹ, ati bi wọn ṣe ja ireti awọn ọmọ Naijiria kulẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, Alaga ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, atawọn gomina kan pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa mi-in lọọ fẹhonu han lọfiisi ajọ INEC to wa niluu Abuja, ti wọn si n beere pe ki ajọ eleto idibo fagi le eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii.

Leave a Reply